Maureen Okpoko
Maureen Okpoko | |
---|---|
Orílẹ̀-èdè | Naijiria |
Iṣẹ́ | Osere |
Ìgbà iṣẹ́ | 2010-iwoyi |
Àwọn ọmọ | 3 |
Maureen Okpoko jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ní ọdún 2016, ó rí yíyàn fún àmì-ẹ̀yẹ Africa Movie Academy fún ẹ̀ka ti òṣèré amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ tí ó dára jùlọ.
Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọdún 2013, ó kópa nínu eré Golden Egg, pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Justus Esiri.[1] Nínu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan ti ọdún 2015, ó sọ di mímọ̀ wípé fíìmù Duplex ni fíìmù tí ó pe òun níjà jùlọ. Nígbàtí ó n sọ̀rọ̀ lóri irú ipa tí kò leè ṣe nínu fíìmù, ó ṣàlàyé wípé òun kì yóò kó ipa oníhòhò. Okpoko ti tún ṣàfihàn nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn eré tẹlifíṣọ̀nù tí Nàìjíríà tó fi mọ́ Dear Mother, Clinic Matters, Neta, University Mafias, Sorrowful Child, Sacrifice the Baby, Red Scorpion àti Baby Oku.[2] Ní ọdún 2015, òun pẹ̀lú Majid Michel àti Beverly Naya jọ kópa nínu eré The Madman I Love.[3] Okpoko tún jẹ́ ọ̀kan nínu àwọn òṣèré tí ó kópa nínu eré Uche Jombo kan tí àkọ́lé rẹ̀ n jẹ́ Good Home (2016), pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Okey Uzoeshi àti Ṣeun Akíndélé. Fíìmù náà dá lóri ṣíṣe àlàyé gbígbé ọmọènìyàn fi ṣiṣẹ́, pẹ̀lú bí ó ti ṣe n ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà.[4]
Ìgbé ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Okpoko jẹ́ ọmọ abínibí ti Ìpínlẹ̀ Anámbra. Ó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti orílẹ̀-èdè Jamáíkà. Ó ti ṣe ìgbeyàwó, ó sì ti ní àwọn ọmọ mẹ́ta.[5]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Ayinla-Olasukanmi, Dupe (July 6, 2013). "Why my husband doesn’t complain when I am away". The Nation. Retrieved 2017-11-11.
- ↑ Akuki, Alfred (January 17, 2015). "I grew up among boys, can handle men –Okpoko". Daily Independent. Retrieved 2017-11-11.
- ↑ "Check out more photos from upcoming movie starring Majid Michel". Pulse. June 3, 2015. Archived from the original on 2017-11-15. Retrieved 2017-11-12.
- ↑ admin (May 5, 2016). "Nelson Jombo’s New Movie "Good Home" tackles Human Trafficking & More Societal Ills". Bellanaija. "Watch the Trailer". Retrieved 2017-11-12.
- ↑ Ayinla-Olasukanmi, Dupe (July 6, 2013). "Why my husband doesn’t complain when I am away". The Nation. Retrieved 2017-11-11.