Maureen Solomon

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Maureen Solomon
Ọjọ́ìbíMaureen Solomon
23 Oṣù Kejìlá 1983 (1983-12-23) (ọmọ ọdún 39)
Abia State
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́Actress
Ìgbà iṣẹ́2001-2011

Maureen Solomon (tí a bí ní 23 Oṣù kejìlá, Ọdún 1983) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kan tí ó ti kópa nínu àwọn eré ti Nàìjíríà tó ti lé ní ọgọ́rin làkókò ìgbà tò fi n ṣiṣé òṣèré lọ́wọ́. [1][2][3]

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ̀ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Solomon ní ìlú Isuochi, Ìpínlẹ̀ Ábíá, níbi tí ó ti ka ìwé mẹ́fà àti ìwé mẹ́wàá rẹ̀ ní ilé-ìwé Isuochi Primary and Secondary School ti Ìpínlẹ̀ ÁbíáÌpínlẹ̀ Ábíá .

Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Solomon ṣàlàyé nínu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pé òun bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré rẹ̀ ní orí ìpele làkókò ìgbà tí òún wà ní ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. Láti ìgbà náà sì lòwún ti máa n gbàá lérò láti fí iṣẹ́ òṣèré náà ṣiṣẹ́-jeun lọ́jọwájú. Solomon kó ipa àkọ́kọ́ rẹ̀ nínu sinimá ti Nàìjíríà nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún[4] níbi eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Alternative tí olùdarí rẹ̀ sì jẹ́ Lancelot Oduwa Imasuen. Solomon ṣàpèjúwe àkọ́kọ́ àyẹ̀wò rẹ̀ fún fíìmù Alternative gẹ́gẹ́ bi ǹkan tó wáyé látara àṣìṣe Lancelot Oduwa Imasuen tí ó ṣìí mú fún ọ̀kan nínu àwọn tí wọ́n forúkọsílẹ̀ fún àyẹ̀wò náà. Ó sọ di mímọ̀ wípé ₦2000 ni wọ́n san fún òun fún ipa tí òún padà kó nínu eré náà ní ọdún 2001.[5][6] Solomon dáwọ ṣíṣe fíìmù ti Nàìjíríà dúró ní ọdún 2011.[7]

Ọ̀rọ̀ ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Solomon ṣe ìgbeyàwó pẹ̀lú Ọ̀gbẹ́ni Okereke, ọkùnrin Dọ́kítà Ìṣègùn kan, wọ́n sì ti jọ bí àwọn ọmọ méjì.[8][9][10]

Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 • Heart Of Stone (2010)
 • Kiss The Dust (2008)
 • Angel Of My Life (2007)
 • Careless Soul (2007)
 • Final War (2007)
 • Help Me Out (2007)
 • Men On Hard Way (2007)
 • Total War (2007)
 • Leap Of Faith (2006)
 • The Lost Son (2006)
 • The Snake Girl (2006)
 • Tomorrow Lives Again (2006)
 • Without Apology (2006)
 • Baby Girl (2005)
 • Blood Battle (2005)
 • C.I.D (2005)
 • Desperate Love (2005)
 • Diamond Forever (2005)
 • Forgiveness (2005)
 • Love Is A Game (2005)
 • Home Apart (2005)
 • Marry Me (2005)
 • My School Mother (2005)
 • Red Light (2005)
 • Rising Moon (2005)
 • Songs of Sorrow (2005)
 • Suicide Lovers (2005)
 • Test Of Manhood (2005)
 • Expensive Game (2005)
 • Coronation (2005)

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 1. "Maureen Solomon". IMDb. Retrieved 2019-12-07. 
 2. "Nollywood actress Maureen Solomon is pregnant after 12 years, flaunts baby bump". www.msn.com. Retrieved 2019-12-07. 
 3. Okundia, Jennifer (2019-04-09). "Maureen Solomon welcomes 2nd child after 12 years". P.M. News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-12-07. 
 4. Owolawi, Taiwo (2018-11-14). "6 things to know about Nollywood actress Maureen Solomon". www.legit.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2019-12-07. Retrieved 2019-12-07. 
 5. RITA (2019-04-09). "After almost 12 years, actress Maureen Solomon welcomes another child". Vanguard Allure (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-12-07. 
 6. "6 things to know about Nollywood actress Maureen Solomon". Within Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-11-14. Retrieved 2019-12-07. 
 7. "In Search Of These Acting Celebrities". guardian.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-12-07. 
 8. RITA (2019-04-09). "After almost 12 years, actress Maureen Solomon welcomes another child". Vanguard Allure (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-12-07. 
 9. Rapheal (2018-04-21). "Why I stopped acting for 7 years –Maureen Solomon, actress". The Sun Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-12-07. 
 10. "Actress, Maureen Solomon Shows off Aged Mother with Great Swag". Nigerian Voice. Retrieved 2019-12-07.