Mayen Adetiba

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Mayen Adetiba
Ọjọ́ìbí1954
IbùgbéLagos
Orílẹ̀-èdèNigeria
Ẹ̀kọ́Columbia University
Iṣẹ́Civil Engineer
Gbajúmọ̀ fúnNigerian woman engineer
Olólùfẹ́Dele Adetiba
Àwọn ọmọ3

Mayen Adetiba (tí a bí ní ọdún 1954) tí ń ṣe ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ òṣèré tí ó wá padà di ògbóǹkarìgì onímọ̀ ẹ̀rọ.

Ìgbésí ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Adebita ni ọdún 1954 sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1] Iṣẹ́ tó ní ṣe pẹ̀lú ṣíṣàkọ́ọ́lẹ̀ owó ni ó fẹ́ kọ́kọ́ ṣe àmọ́ ó padà nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ ìmò ẹ̀rọ.[2] Ó fẹ́ Délé Adetiba, wọ́n sì bí ọmọ mẹ́ta, Kemi Adetiba jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ wọn tí wọ́n bí sí ìpínlẹ̀ Èkó ní ọdún 1980.[3]

Iṣẹ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Adetiba ti fìgbà kan jẹ́ òṣèré ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó ṣiṣẹ́ lórí The Bar Beach Show, ó sì ṣe ìyàwó Lákúnlé Òjó nínú eré Village Headmaster. Ó kópa nínú fíìmù Kongi Harvest tí ó jáde ní ọdún 1980. [2] A yàn-án gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Association of Consulting Engineers of Nigeria, ó sì jẹ́ ìgbà kejì Ààrẹ ti Nigerian Society of Engineers nígbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.[4] Òun ni obìnrin àkọ́kọ́ tí wọ́n fi ṣe ọ̀kan lára àwọn Executive Committee ni Nigerian Society of Engineers. [3] Kíkọ́ African Union Southern Africa Regional Office tí ó wà ní Malawi àti Summerhill Baptist Church ní ìpínlẹ̀ Èkó jẹ́ àwọn iṣẹ́ tí ó ti ṣe. Ó tún ṣiṣẹ́ lórí pro bono tí wọ́n kọ́ ṣìkejì.[2]

Ètò Ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ilé ẹ̀kọ́ gíga ní òkè òkun ni ó lọ. Níbi tí ó tí ń ṣiṣẹ́ láti rán ara ẹ̀ lọ ilé-ìwé nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ ò rówó ránṣẹ́ si nítorí àwọn ìdojúkọ kan. Ó wà ní New York University fún ìgbà díè kí ó tó gba ìsọdá sí Columbia University níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Electrical Engineering. Civil Engineering ni ó padà ṣe nígbà tí wọ́n sọ fún pé Civil Engineering nìyí ní ilẹ̀ Áfíríkà.[2]

Nígbà tí ó yí ohun tí ó ń kọ́ ní Ifásitì náà sí Civil Engineering, ó já sí pé Adetiba nìkan ni ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti aláwọ̀ dúdú tí ó ń kọ́ ẹ̀kọ́ náà.[4] Ó tẹ̀ síwájú láti gboyè Master's Degree ní Cornell University.[2]

Ní ọdún 2017, ó fojú hàn lórí ètò kan tí ọmọ rẹ̀ Kemi gbé kalẹ̀ tí ń jẹ́ "King Women". Ó dara pọ̀ mọ́ àwọn King Women mìíràn bí i Chigul, Taiwo Ajai-Lycett, TY Bello àti Tara Durotoye[5]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Admin (2016-08-22). "ADETIBA, Mayen Modupeola,". Biographical Legacy and Research Foundation (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-04-24. 
  2. 2.0 2.1 2.2 2.3 2.4 Published. "I set out to study accountancy, but graduated as an engineer –Adetiba". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-04-24. 
  3. 3.0 3.1 "3 solid reasons why Kemi Adetiba's 'King of Boys' should NOT have been a hit". www.pulse.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-11-07. Retrieved 2020-04-24. 
  4. 4.0 4.1 "There were just two of us in class — Mayen Adetiba, renowned Civil Engineer". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2016-05-12. Retrieved 2020-04-24. 
  5. "Mayen Adetiba speaks on how she dealt with patriarchy at work on the latest episode of King Women". ID Africa (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-06-28. Archived from the original on 2022-03-07. Retrieved 2020-04-24.