Mbeki Mwalimu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Mbeki Mwalimu jẹ́ òṣèré ará Kenya, olùdásílẹ̀ àti olùdarí tí ó ju ọdún mẹ̀wá lọ nínú eré ìtàgé àti ìrírí TV. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ ní ibi ìṣeré ti Kenya ní ọdún 2004 ní Mbalamwezi Players ṣaájú kí ó darapọ̀ mọ́ Festival Of Creative Arts (FCA) ní ọdún 2007 àti pé láti ìgbà náà, ó ti di orúkọ tí a mọ̀ mó ọ gẹ́gẹ́ bí òsèré orí ìtàgé àti eré oníse, olùṣàkóso ìṣelọ́pọ̀, olùdarí eré orí ìtàgé àti olùdásílẹ̀.

Ò jẹ́ olókìkí fún àwọn eré orí ìtàgé làárín FCA àti fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Zoe Mackenzie nínú eré Swahili telenovela Selina ní ọdún 2018 lórí Maisha Magic àti pé ó tún se ìfihàn nínú eré <a href="https://en.wikipedia.org/wiki/Sincerely_Daisy" rel="mw:ExtLink" title="Sincerely Daisy" class="cx-link" data-linkid="8">Sincerely Daisy</a>, èyítí ó ṣe àfihàn lórí Netflix ní Ọjọ́ kẹ̀sán Oṣù Kẹ̀wá , Ọdún 2020.

Iṣẹ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó ti ṣiṣẹ́ bí olùgbékalẹ̀ èto TV ní Kenya Broadcasting Corporation tí ó sì jẹ́ olóòtú èto Good Morning Kenya àti The Ultimate Choir .

Ó bẹ̀rẹ̀ ìpìlẹ aṣọ ìtàgé rẹ̀ Padà sí ìpìlẹ̀ ní ọdún 2018, pẹ̀lú èrò láti kópa nínú ìdàgbà sókè ìgbésí ayé eré orí ìtàgé ní Kenya.

Ó tún jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ kan ní Kenya Actors Guild (KAG).

Ó bẹ̀rẹ̀ The Mbeki Mwalimu Initiative (TMI), ìpìlẹ̀ kan tí ó gbèrò láti yí ìgbésí ayé àwọn ọmọ tó nílò ìrànlọ́wọ́ nípasẹ̀ ìpèse ohun èlò àti ìmọ̀ràn.

Àwọn Ààmì Ẹ̀yẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó gba ààmì ẹ̀yẹ Olùdarí eré orí ìtàgé tí ó dára jùlọ ní ọdún 2018 - Ààmì Ẹ̀yẹ Sanaa.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]