Jump to content

Mufutau Gbadamosi Esuwoye II

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Mufutau Gbàdàmọ́sí Èsúwọyè II tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹjọ, ọdún 1963 jẹ́ Ọba Ọlọ́fà ti ìlú Ọ̀fà ẹlẹ́kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní Ìpínlẹ̀ Kwara ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà .[1]

Wọ́n bí Mufutau Gbadamosi Esuwoye kejì ní ọjọ́ Kẹwàá oṣù keje ọdún 1963 sí ẹbí Alhaji Muhammed Gbadamosi Esuwoye àti Alhaja Awawu Gbadamosi Esuwoye, ti ìdílé Obatiwajoye àti Asalofa ní ìjọba ìbílẹ̀ Ọ̀fàÌpínlẹ̀ Kwara ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ọba Mufutau, lọ sílé ẹ̀kó Maru Teachers College, tí ó wà ní ìlú Gusau, láàrín ọdún 1976 sí 1981, níbi tí ó ti gba ìwé-ẹ̀rí Olukoni grade II. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Birni-Kebbi láàrín ọdún 1982 àti 1985 fún ìwé-ẹ̀kọ́ gíga ti orílẹ̀-èdè (ND) nínú ìmọ̀-ilé. Ní ọdún 1989 ó gba oyè nínú ìmọ̀-ẹ̀rọ Ilé láti Ile-ẹkọ giga Ahmadu Bello, ní ìlú Zaria.

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2023-12-24. Retrieved 2023-12-24.