Muhammad Nami

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Muhammad Nami jẹ́ Alága aṣẹ̀ṣẹ̀yàn fún àjọ ìjọba-àpapò lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó ń ṣe kòkárí fún owó-orí gbígbà, FIRS. Lọ́jọ́ kẹsàn-án oṣù Kejìlá ọdún 2019 ni Ààrẹ Muhammadu Buhari ṣẹ̀ṣẹ̀ fi orúkọ rẹ̀ ránṣẹ́ sí ilé-ìgbìmọ̀-aṣòfin-àgbà fún ìfọwọ́sí. Nami ni yóò rọ́pò Babátúndé Fowler, tí ó jẹ́ Alága àjọ Federal Inland Revenue Service, FIRS, ṣùgbọ́n tí fẹ̀híntì lọ́jọ́ kẹsàn-án oṣù Kejìlá ọdún 2019. [1] [2]

Ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọ̀gbẹ́ni Nami jẹ́ gbajúgbajà onímọ̀ nípa owó-orí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ile iṣẹ́ àti ìjọba lóríṣiríṣi tí Nami tí ṣiṣẹ́ ṣíṣe kòkárí àti ìgbaninímọ̀ràn lórí owó-orí fun. Muhammad Nami kàwé gboyè dìgírì nínú ìmò àyíká (Sociology) ní ifáfitì Bayero University ní ìlú Kano lọ́dún 1991 àti Ahmadu Bello University ní ìlú, Zaria lọ́dún 1991, níbi tí ó ti gba dìgírì kejì, Masters of Business lọ́dún 2004. Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Chattered Institute of Taxation of Nigeria, Institute of Debt Recovery Practitioners of Nigeria àti Associate Member of Nigerian Institute of Management (Chartered) pelui Association of National Accountants of Nigeria. [3] [4]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Nseyen, Nsikak (2019-12-09). "FIRS: Profile of nominated chairman, Muhammed Nami - Daily Post Nigeria". Daily Post Nigeria. Retrieved 2019-12-09. 
  2. "PROFILE: Muhammad Nami, a tax consultant, heads Nigeria's FIRS". Premium Times Nigeria. 2019-12-09. Retrieved 2019-12-09. 
  3. Published (2015-12-15). "10 things to know about new FIRS chairman, Muhammad Nami". Punch Newspapers. Retrieved 2019-12-09. 
  4. Olaniyi, Joshua Odeyemi & Muideen (2019-12-09). "11 things you should know about Muhammad Nami, Buhari's nominee to head FIRS – Daily Trust". Daily Trust. Retrieved 2019-12-09.