Federal Inland Revenue Service

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Federal Inland Revenue Service tí apèkúrú rẹ̀ ń jẹ́ FIRS jẹ́ ilé-iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ tí ó ń ṣe kòkárí ètò owó-orí àti gbígbà rẹ̀.[1] Ọ̀gbẹ́ni Muhammad Nami ni Alága-aṣẹ̀ṣẹ̀yàn fún ilé iṣẹ́ agbowó-orí yìí. Ààrẹ Muhammadu Buhari kéde yíyàn rẹ̀ lọ́jọ́ Kẹsàn-án oṣù Kejìlá ọdún 2019.[2] Ẹni tí ó wà nípò Alága ilé iṣẹ́ yìí títí di ọjọ́ yìí ni Ọ̀gbẹ́ni Babátúndé Fowler, tí sáà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Alága ilé iṣẹ́ agbowó-orí parí lọ́jọ́ kẹsàn-án oṣù Kejìlá ọdún 2019. [3]

Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ilé iṣẹ́ agbowó-orí yìí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n dá ilé-iṣẹ́ agbowó-orí yìí sílẹ̀ ní apá àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́dún 1902 nígbà tí Òyìnbó Amúmisìn Sir Fredrick Lugard ń ṣe àkóso orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní agbègbè náà.[4] Èyí ṣẹlẹ̀ kí ìdarapọ̀ tó wáyé láàárín apá àríwá àti gúsù (Amalgamation of Northern and Southern Nigeria) orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lọ́dún 1914. Ní àsìkò yìí, ilẹ̀ iṣẹ́ yìí wà lábẹ́ ìṣàkóso ìjọba orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì, nítorí àwọn ló ń mú wá sìn nígbà náà, oríṣiríṣi àtúnṣe ló sìn wáyé lórí ilẹ̀-iṣẹ́ owó orí gbígbà yìí, Ṣùgbọ́n lọ́dún 1943, ìjọba Amúmisìn orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì ṣòfin tuntun láti jẹ́ kí ilé iṣẹ́ yìí dá dúró fún ara rẹ̀ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, wọ́n sìn fún un ní orúkọ tuntun tí wọ́n pè ní Federal Board of Inland Revenue. Lẹ́yìn èyí onírúurú àtúnṣe ló tún ti wáyé lórí ilẹ̀ ìṣe owó orí gbígbà yìí. Nígbà tí ó di ọdún 2007 lábẹ́ ìṣàkóso ìjọba Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ ni wọ́n sọ ọ́ ni orúkọ Federal Inland Revenue Service yìí. Oríṣiríṣi àtúnṣe àti àgbéyẹ̀wò ló sìn ti wáyé lórí ilẹ́-iṣẹ́ agbowó-orí yìí títí di àsìkò tí a wà yìí.[5]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Weco system (2012-07-23). "Federal Inland Revenue Service(FIRS) Network Infrastructure Project". WECO Systems International Limited. Retrieved 2019-12-10. 
  2. "UPDATED: Fowler out as Buhari appoints new chairman for FIRS". Premium Times Nigeria. 2019-12-09. Retrieved 2019-12-10. 
  3. "Babatunde Fowler, Executive Chairman, Federal Inland Revenue Service (FIRS) : Interview". Oxford Business Group. 2018-12-05. Retrieved 2019-12-10. 
  4. "FIRS". FIRS. 2019-12-10. Retrieved 2019-12-10. 
  5. Ngcareers (2016-04-20). "Working at Federal Inland Revenue Service (FIRS) - Overview and Employee Reviews". Ngcareers. Retrieved 2019-12-10.