Mwai Kibaki

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Mwai Kibaki
Mwai Kibaki, February 2012
Aare ile Kenya
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
30 December 2002
Alákóso ÀgbàRaila Odinga
Vice PresidentMichael Wamalwa Kijana
Moody Awori
Kalonzo Musyoka
AsíwájúDaniel arap Moi
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí15 Oṣù Kọkànlá 1931 (1931-11-15) (ọmọ ọdún 92)
Gatuyaini, Kenya
Aláìsí21 April 2022
Ẹgbẹ́ olóṣèlúPNU
(Àwọn) olólùfẹ́Lucy Kibaki

A bí Kìbákì ní ọjọ́kẹ̀ẹ̀ẹ́dógún oṣù kọ́kànlá ọdún (1931-2022) Orúkọ ìbatisi rẹ̀ ni Emilio Stanley ṣùgbọ́n kò pé tí ó fi orúkọ yìí sílẹ̀ tí ó ń jẹ́ orúko kìkúyí. Òjíṣẹ́ Ọlọ́run kan ara Ítálì ni ó sà á lámì. Ọmọ ìjọ Àgùdà (Catholic) ni Kìbákì. History àti Political Science ni ó kà ní Màkéréré University ní Kampala, Uganda. Òun ni ó ṣ eipò kìíní nínú kíláàsì rẹ̀ nígbà tí ó jáde ní 1955. Ó fi ẹ̀kọ́-òfẹ̀ lọ London School of Economics níbi tí ó ti ka Public finance tí ó sì gboye B.Sc ní 1959. Ó pada sí makerere. Ó ṣe iṣẹ́ olùkọ́ díẹ̀ kí ó tó fi iṣẹ́ náà sílẹ̀ lọ máa ṣe òṣèlú. Ó gbé àpótí ó wọlé sí ilé aṣòfin. Wọ́n jọ dá ẹgbẹ́ Kenya African National Union (KANU) sílẹ̀ ni ní 1960 Lẹ́yìn ọdún méjì tí ó ti wà nílé aṣòfin,wọ́n sọ ọ́ di Minister of Commerce and Industry. Nígbà tí Arap Moi di àrẹ lẹ́yìn ikú Jomo Kenyatta ní 1978, ó di igbá kejì àrẹ. Ní ọdún 1990, ó dá ẹgbẹ́ tirẹ̀ tí ó ń jẹ́ Democratic Party sílẹ̀ Ní ọdún 2002, ó di ààrẹ Kenya.



Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]