Raila Odinga

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí
Raila Amollo Odinga
Raila Odinga, 2009 World Economic Forum on Africa-1.jpg
Odinga attending the 2009 World Economic Forum on Africa, June 2009.
Prime Minister of Kenya
Lọ́wọ́
Ó bọ́ sí orí àga
17 April 2008
President Mwai Kibaki
Asíwájú Jomo Kenyatta (1963 – 1964)
Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́
Ìbí 7 Oṣù Kínní 1945 (1945-01-07) (ọmọ ọdún 72)
Maseno, Kenya
Ẹgbẹ́ olóṣèlú ODM
Tọkọtaya pẹ̀lú Ida Odinga (born 1950)
Ẹ̀sìn Anglican

Raila Amollo Odinga (born January 7, 1945) je oloselu omo ile Kenya, lowolowo o je Alakoso Agba ile Kenya ninu ijoba idarapo.

A bí i ní Maseno, Kizumu District, Nyanza Prorince ní January 1945. Ó rí èkó-òfé ní 1965 èyí tí ó fi lo kàwé ní Technical University of Magdeburg (tí ó jé ara Otto von Gueriche University of Magdeburg) ní East Germany. Ní odún 1970, ó jáde ó si gba oyè lórí Mechanical Engineening. Nígbà tí ó dé Kenya, ó se olùkó ní University of Naírobì kí ó tó lo máa se òsèlú. Ní odún 1975, wón so ó di Deputy Director of the Kenya Burean of Standards isé tí ó se títí tí wón fi so ó sí ìhámó ní 1982. Wón fi i sílè ní osù kefà 1988, wón tún tún un mú ní osù kéjo. Wón fi sílè ní ojó kejìlá osù kéfà 1989 wón tún mú un padà ní ojó karùn-ún osù kéje odún 1990 pèlú Keneth Matiba àti Charles Rubia. Bí wó se dá a sílè ní ojó kokàndínlógún osù kefà odún 1991, nse ni ó sá gba Norway lo Ó ní wón fé pa òun. Ó padà sí Kenya ní 1992, ó dara pò mó egbé òsèlú FORD eyí tí baba re, Jaramongi Oginga Odinga n darí. Nígbà tí bàbá rè kú ní osù kìíní odún 1994 tí Michacl Waimalwa kijana di olórí egbé náà Raila ta kò ó sùgbón ó fidí remi èyí ló mu un (Raila) kúrò nínú egbé náà tí ó sì lo dara pò mó National Development Party (NDP).


Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]