Níyì Adéolókun

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Àdàkọ:Infobox rugby biography

Níyì Adéolókun tí wọ́n bí ní ọjọ́ Kẹ́ta oṣù Kọkànlá ọdún 1990 ( 3 November 1990) jẹ́ agbá bọ́ọ̀lù rugby fún  (Irish rugby union). Ó ń gbá fún wọn gẹ́gẹ́ bí onígun  (winger). Adéolókun ló tún ń gbá rugby fún ikọ̀ ( Connacht) ní  Pro14. Ó dara pọ̀ mọ́ Connacht ní ọdún 2014 láti ilé-ẹ̀kọ́ 'Trinity College'. Lásìkò tí ó fi wà pẹ̀lú ilé-ẹ̀kọ́ àgbà ti  (Dublin University), Ó gbá rugby sevens fún ikọ̀ ilé-ẹ̀kọ́ náà.

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Adéolókun ní ìlú Ìbàdàn,ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Ó lọ sí ilẹ̀ Ireland pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀ ní ọ̀dún 2001 nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mọ́kànlá (age 11). Ó ń ṣe oríṣiríṣi eré ìdárayá nígbà tí ó wà léwe. Ó gbá bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀-gbá fún Gaelic football àti Templeogue Synge Street tí ó sì tún gbá bọ́ọ̀lù fún League of Ireland àti  Shelbourne's tí ọ̀jẹ̀-wẹ́wẹ́ tí ọjọ́ orí wọn kò ju ogún ọdún lọ (under 20).[1] Ó kọ́kọ́ gbá fún  rugby union  gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ ní  De La Salle College ní Churchtown.[2]

Iṣẹ́ òòjọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

ìgbà ̀ewe rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Adéolókun gbá fún Leinster nígbà èwe rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó kúrò níbẹ̀, ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ De La Salle tí ó jẹ́ ikọ̀ àgbà fụn ilé-ẹ̀kọ́ náà. Ní ọdún 2009,  All-Ireland League nílé ìwé Dublin University bá fìwé pèé lábẹ́ àṣẹ olùdarí bọ́ọ̀lù Rugby ìyẹn Tony Smeeth. Adeólókun gbá bọ́ọ̀lù yíi fún ikọ̀ náà fún ọdún mẹ́rin. Lásìkò tí ó wà níbẹ̀, ikọ̀ nạ́à gba ife ẹ̀yẹ 'All-Ireland Championships' ní tẹ̀lé-ǹ- tẹ̀lé ní ọdún 2011 àti 2012.

Connacht[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní oṣù Kárùún ọdún 2014, wọ́n kéde rẹ̀́ wípé Adéolókun fọwọ́ sí ìwé àdéhùn pẹ́̀lú (Connacht) ikọ̀ rẹ̀ tí ó wà yíi tí ó jẹ́ ọlọ́dún kan. Olùkọ́ni Nigel Carolan ni ó tọ́ka rẹ̀ fún ilé-ẹ̀kọ́ náà, lẹ́yìn tí ó ti yege nínú ìdánwò rẹ̀ ní Connacht Eagles, ní oṣù Kẹ́rin ọdún 2014.[3]

Adéolókun fakọyọ fún ikọ̀ rẹ̀ (Connacht) ní ọjọ́ Kẹfà oṣù Kẹ́sàạn ọdún 2014, nígbà tí wọ́n gbá pẹ̀lú ikọ̀  Newport Gwent Dragons nị́bi ìfẹsẹ̀-wọnsẹ̀ ìṣíde òpin ọ̀sè ní 2014–15 Pro12, níbi tí ó tí ṣe ìrànwọ́ fún akẹgbẹ́ rẹ̀ Eoin McKeon . Ọ́ tún gbá bọ́ọ̀lù àkọ́kọ́ rẹ̀ sínú àwọn lẹ́yìn ìfọwọ́ bọ̀wé rẹ̀ nị́gbà tí wọ́n gbá pẹ̀lú ikọ̀ La Rochelle níbi ìdíje 2014–15 Rugby Challenge Cup. Gbogbo bọ́ọ̀lù tí ó gbá nínú ìdíje league jẹ́ mẹsàán tí ti Challenge Cup sì jẹ́ mẹ́rin nínú ìpele ìbẹrẹ̀ ọdún.[4][5]  Ní oṣù Kọkànlá ọdún 2014, wọ́n kéde rẹ̀ wípé  Ó tún fọwọ́ bọ̀wé àdéhùn míìràn pẹ̀lú ikọ́̀ rè yíi Connacht láti wà pẹ̀lú ikọ̀ náà títí di òpin ọdún  2016–17.[6]

Ní 28 May 2016, (Connacht) gba ife ẹ̀yẹ àkọ́kọ́ irú rẹ̀ nị́  2015–16 Pro12 lẹ́yìn tí wọ́n jạwé olúborí pẹ̀lú ayò 20 sí 10 tako Leinster níbi ìfẹsẹ̀-wọnsẹ̀ tó kẹ́yìn ìdịje náà. tí Adéolókun sì gbá àmì ayò náà wọlé.[7]

Ireland[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

November, 2016 Adéolókun gba ìwé ìpè àkọ́kọ́ rẹ̀ láti dara pọ̀ mọ́ ikọ̀ àgba bọ́ọ̀lù àgbà fún ilẹ̀  Ireland.[8] Ó sì fakọ yọ nínú ikọ̀ náà ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Kọkànlá ọdún  2016, nígbà tí wọ́n fi rọ́pò akẹgbẹ́ rè Craig Gilroy tako ikọ̀ agbá rugby ilẹ̀ Canada.[9]

Àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Analysis: Connacht's sensational attack brings them Pro12 glory". The42. 29 May 2016. Retrieved 30 August 2016. The 25-year-old has a rich sporting background in Gaelic football with Templeogue Synge Street and soccer – having played for Shelbourne’s U20 side 
  2. "From AIL to PRO12 for speedy Adeolokun". Connacht Rugby. 12 September 2014. Retrieved 11 September 2015. 
  3. "Connacht bring in Adeolokun". Setanta Sports. 16 June 2014. Retrieved 11 September 2015. 
  4. "Connacht Squad Index: Niyi Adeolokun". Pro12. Retrieved 11 September 2015. 
  5. "Player Archive: Niyi Adeolokun". EPC Rugby. Retrieved 11 September 2015. 
  6. "Connacht extend Niyi Adeolokun contract". RTÉ Sport. 26 November 2014. 
  7. "2016 Pro12 Final: as it happened". The 42. 28 May 2016. Retrieved 31 May 2016. 
  8. "Jordi Murphy: Ireland flanker out for 'six to nine months' because of knee injury". BBC. 7 November 2016. https://www.bbc.co.uk/sport/rugby-union/37901414. Retrieved 7 November 2016. 
  9. "Connacht influence strong as Schmidt's Ireland run eight tries past Canada". The42. 12 November 2016. Retrieved 12 November 2016.