Nana Abdullahi
Nana Abdullahi | |
---|---|
High Court judge | |
In office Ọdun 2010 – Ọjọ́ Kàrún oṣù kẹta ọdun 2014 | |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 1960 |
Aláìsí | 5 Oṣù Kẹta 2014 |
Aráàlú | Nàìjíríà |
Nana Aisha Abdullahi (tí a bí ní ọdun 1960 tí ó sì fi ayé sílè ní ọjọ́ kàrún-ún oṣù kẹta ọdún 2014) jẹ́ adájọ́ àti agbejọ́rò tẹ́lẹ̀rí ní Nàìjíríà. Ní ọdún 2010, Abdullahi di adájọ́ High Court ìpínlè Jigawa, òun sì ni obìnrin àkọ́kọ́ tó máa kọ́kọ́ dé ipò náà.[1] (Jigawa jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ìpínlẹ̀ ní apá Àríwá orílè-èdè Nàìjíríà.)
Abdullahi jẹ́ Solicitor General, Attorney General àti Commissioner for Justice láti 2000 sí 2005.[2] A yàn án gẹ́gẹ́ bi adájọ́ àgbà ti ilé-ẹjọ́ gíga ní ìpínlè Jigawa, ní ọdun 2010, òun sì ni obinrin àkọ́kọ́ tí ó di ipò náà mú. Òun ni ó di ipò yìí mú títí di ìgbà tí ó fi ayé sílè ní ọdún 2014.
Justice Nana Abdullahi fi ayé sílè ní ilé-ìwòsàn aládàáni kan ní Dutse, ìpínlè Jigawa, Nàìjíríà, ní ọjọ́ kàrún-ún oṣù kẹta ọdún 2014 ní ọmọ ọdún mẹ́rìnléláàádọ́ta. Ó fi ọkọ rẹ̀, Abubakar, sílẹ̀ sáyé.
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Jigawa's first female High Court judge dies at 54". Daily Post (Nigeria). 2014-03-08. http://dailypost.ng/2014/03/08/jigawas-first-female-high-court-judge-dies-54/.
- ↑ "Justice Nana Aisha Abdullahi Is Dead: Jigawa's 1st Female Chief Magistrate Dies - Proudly Nigerian DIY Motivation & Information Blog". NaijaGists.com - Proudly Nigerian DIY Motivation & Information Blog. 2014-03-08. Retrieved 2023-03-10.