Ndagi Abdullahi
Ndagi Abdullahi jẹ́ olùkọ́àgbà ní Nàìjíríà, òǹkọ̀wé, àti Alága (CEO) KinNupe Newspaper. Abdullahi jẹ́ ọmọ Nupe ní èdá àti pé ó ti kópa nínú kíkọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àròkọ nípa àṣà àti àgbékalẹ̀ ayé àwọn Nupé.
Ọnà ìgbé ayé
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wón bí Ndagi Abdullahi ní ọjọ́ kẹjọ, Oṣù Kejìlá, ọdún 1972 ní Ṣọ̀kọ́tọ́, sí àwọn òbí tó jẹ́ ọmọ Nupe láti Bida. Ó gba ẹ̀kọ́ ilé-ékó́ ìpìlẹ̀ àti girama rẹ̀ ní Minna, Ìpínlẹ̀ Niger, lẹ́yìn náà ló tẹ̀síwájú sí àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti ní òkèèrè.[1]
Abdullahi, tí ó kọ́kọ́ kọ́ ìṣẹ́ dókítà, ṣe ayípadà sí ìṣẹ́ òǹkọ̀wé. Ó ti lo tó ọ̀gbọ́n ọdún nínú ìkọ̀wé, ìwádìí, àti kíkọ́ ní gbogbo àbùjá àwọn ìtàn ìran àti àṣà Nupe. Ó ti kọ́ àwọn ìwé tó lé ní ọgọ́rùn ún mẹ́tà (300), púpọ̀ nínú wọn ni wọ́n tẹ̀ jáde ní ọdún 2021, tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa ìtàn Nupé, èdè, àti bẹ̀bẹ̀lọ́.[1]
Ó jẹ́ Alága Nupe Cultural and Resource Centre (NCRC), ilé-iṣẹ́ ìwádìí Nupe gíga kan tó wà ní Ìpínlẹ̀ Niger, tí Alhaji Yahaya Abubakar, tí ó jẹ́ Etsu kẹtàlá, dá sílẹ̀.[2]
Ní ọdún 2021, ọbá aláṣẹ Alhaji Dr. Yahaya Abubakar, tí ó jẹ́ Etsu Nupe fí Abdullahi jẹ́ Amana Nupe.[3]
Nínú àwọn iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- (2021). Aminu: The African Ancestry of Prophet Muhammad.[4]
- (2021). Oduduwa Was Nupe: How the Yoruba People Originated from Nupe.[5]
- (2021). Nupe Zam: Pre-Colonial Histories of Nupe Tribal Sections.[6]
- (2021). Gbarazhi: Histories of Some Emirates and Towns in KinNupe.[7]
- (2021). Edu State: The Case of a Homeland State for the Nupe Nation[8]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 "Ndagi Abdullahi". Minna City of Literature. 22 September 2023.
- ↑ Oji Onoko (30 March 2014). "Nigeria: Nupe as Epicentre of Nigerian Arts". All Africa Stories.
- ↑ "Turbaning Ceremony Of Eminent Persons At Bida Emirate In Niger State". yemiosinbajo.ng. 4 December 2021.
- ↑ Ndagi, Abdullahi (2021). Aminu: The African Ancestry of Prophet Muhammad. KDP Print US. ISBN 979-85163869-9-2.
- ↑ Ndagi, Abdullahi (2021). Oduduwa Was Nupe: How the Yoruba People Originated from Nupe. KDP Print US. ISBN 979-85027219-8-1.
- ↑ Ndagi, Abdullahi (2021). Nupe Zam: Pre-Colonial Histories of Nupe Tribal Sections. KDP Print US. ISBN 979-85051652-9-4.
- ↑ Ndagi, Abdullahi (2021). Gbarazhi: Histories of Some Emirates and Towns in KinNupe. KDP Print US. ISBN 979-85047451-8-3.
- ↑ Ndagi, Abdullahi (2021). Edu State: The Case of a Homeland State for the Nupe Nation. KDP Print US. ISBN 979-85037320-8-5.