Jump to content

Nigeria Sexual offenders and Service Provider Database

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Nigeria Sexual offenders and Service Provider Database tí ó wà lábẹ́ ìṣàkóso NAPTIP jẹ́ olùpèsè iṣẹ́ tó ní ojúṣe láti ṣe àtòjọ àti àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn èèyàn tí wọ́n ti fi ẹ̀sùn ìwà-ipá kàn, àti ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n gan-an. Àwọn èèyàn tó bá ti lòdì sí àwọn òfin tó wà lábẹ́ Section 44, nínú ìwé àkójọpọ̀ òfin orílẹ̀-èdè Naijiria ni àjọ yìí máa ń .[1] Ohun tí àwọn òfin yìí wà fún gan-an ni; [2][3]

  • láti dẹ́kun ìwà-ipá níkọ̀kọ̀ àti nígnangba
  • láti ṣe ìdíwọ́ sí ìwàkíwà tàbí ìwà-ipá sí èèyàn
  • láti pèsè ààbò tó péye, àti ojútùú tó múnádóko fún àwọn olùfaragbá
  • àti láti ṣe ìjìyà tó tọ́ fún àwọn ẹlẹṣẹ̀

Ọdún 2015 ni wọ́n gbé ètò yìí kalẹ̀ lábẹ́ òfin tó ń rí sí dídí ìwà-ipá lọ́wọ́, ààrẹ Goodluck Jonathan ló sì bọwọ́ lu ìwé yìí.[4] Kí wọ́n tó gbétò yìí kalẹ̀ lọ́dún 2019, àkọsílẹ̀ méjì péré ni ó wà fún ṣíṣe àtòjọ orúkọ àwọn èèyàn tí wọ́n ti fi ẹ̀sùn ìwà-ipá kàn, àwọn ìwé náà ni; the Sexual Offenders Registry ní Ipinle Eko àti the Black book Ìpínlẹ̀ Èkìtì[5]

Àwọn abala àkọsílẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn abala àkọsílẹ̀ tí ó wà ni;

  • Abala àwọn ẹjọ́ tí wọ́n ti ṣe ìdájọ́ sí. Èyí ń tọ́ka sí àwọn ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ tí ilé-ẹjọ́ sì ti dájọ́ fún.
  • Abala àwọn ẹ̀sùn tọ́ ti gbé lọ ilé-ẹjọ́. Èyí ń tọ́ka sí àwọn ẹjọ́ tí wọ́n ti gbé lọ ilé ẹjọ́, tó ń retí ìdájọ́.
  • Àwọn ẹjọ́ tí wọ́n ti fi sùn. Èyí ń tọ́ka sí àwọn ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ tí wọ́n ti mú wá pẹ̀lú ẹ̀rí tó dáńtọ́.
  • Abala tí fọ́ọ̀mù àwọn ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ ìfipábánilòpọ̀ látẹnu àwọn olùfaragbá. Èyí wà fuhn àwọn olùfaragbá láti lè fi ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ tàbí ìwà-ipá sùn nígbàkugbà.

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Nigeria Sexual Offender & Service Provider Database". Nigeria Sexual Offender & Service Provider Registers (in Èdè Latini). 2021-10-21. Retrieved 2022-03-30. 
  2. Website, using this; User, The. "Background Check Service". Nigeria Sexual Offender & Service Provider Database. Retrieved 2022-03-30. 
  3. "NAPTIP – National Agency For The Prohibition Of Trafficking In Persons". NAPTIP – National Agency For The Prohibition Of Trafficking In Persons. 2022-03-08. Retrieved 2022-03-30. 
  4. Gbenga-Ogundare, Yejide (2021-12-14). "Six years after, Nigeria’s VAPP law still struggling for domestication in 17 states". Tribune Online. Retrieved 2022-03-30. 
  5. "Nigeria now has a national sex offenders database". Techpoint Africa. 2019-11-27. Retrieved 2022-03-30.