Nkem Owoh
Nkem Owoh | |
---|---|
Nkem Owoh at the African Movie Academy Awards in Bayelsa State, Nigeria, 2008 | |
Ọjọ́ìbí | Nkem Owoh 7 Oṣù Kejì 1958 Amagu, Udi Town, Eastern Region, British Nigeria (now in Enugu State, Nigeria) |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Orúkọ míràn | Nwabuoku |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Federal University of Agriculture, Abeokuta |
Iṣẹ́ | Actor |
Olólùfẹ́ | Ngozi Owoh |
Nkem Owoh (tí wọ́n bí ní ọjọ́ 7 oṣù February, ọdún 1958) jẹ́ òṣèrékùnrin àti apanilẹ́rìn-ín orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ní ọdún 2008, ó gba àmì-ẹ̀yẹ ti African Movie Academy lábẹ́ ìsọ̀rí "Òṣèrékùnrin tó jẹ́ olú ẹ̀dá-ìtàn tó dára jù lọ", fún àwọn ìkópa rè nínú fíìmù orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, bí i "Stronger than Pain".[1]
Ìgbésí ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ipinle Enugu, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni wọ́n bí Nkem Owoh sí. Lẹ́yìn ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama rẹ̀, ó lọ sí Yunifásítì ìlú Ìbàdàn, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ. Láti ìgbà tó ti wà ní Yunifásiti náà ni ó ti ń kópa nínú fíìmù ṣíṣe.[2]
Iṣẹ́ tó yàn láàyò
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ó tún gbajúmọ̀ fún orin kan tó kọ, tí àkọ́lé rè jẹ́ "I Go Chop Your Dollar", èyí tó sọ̀rọ̀ nípa lílu ènìyàn ní jìbìtì.[3] Àjọ Economic and Financial Crimes Commission gbẹ́sè lé orin náà.[4] Ní ọdún 2007, àwọn ọlọ́pàá mú Owoh ní ìlú Amsterdam, ní Netherlands nítorí àbájáde ìwádìí olóṣù méje tí wọ́n ṣe.[5] Wọ́n mú Owoh ní ibi t́ ti ń kọrin ní ayẹyẹ kan, níbi tí àwọn ọlọ́pàá ti kó ènìyàn 111, nítorí wọ́n fura sí wọn pé wọ́n ń ṣiṣẹ́ jìbìtì, àmọ́ wọ́n padà tú u sílẹ̀.[6][7] Ní oṣù kọkànlá ọdún 2009, àwọn ajínigbé gbé Owoh ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ní apá Ìlà-oòrùn ilẹ̀ náà.[8] Àwọn ajínigbé yìí bèèrè 15 million naira.[9] Wọ́n padà tú Owoh sílẹ̀ nígbà tí àwọn ẹbí rẹ̀ san 1.4 million naira.[10][11]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "AMAA 2008: List of Nominees and Winners". Archived from the original on 2020-10-13. Retrieved 2023-09-07.
- ↑ "Biography of Nkem Owoh". Archived from the original on January 23, 2010. Retrieved 2009-11-11. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Jan Libbenga (2007-07-02). "'I Go Chop Your Dollar' star arrested". The Register.
- ↑ "Police Arrest Nkem Owoh in Holland". NigeriaMovies.net. 2007-07-04. Archived from the original on 2016-03-04. Retrieved 2023-09-07.20
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ "Police Arrest Nkem Owoh in Holland". NigeriaMovies.net. 2007-07-04. Archived from the original on 2016-03-04. Retrieved 2023-09-07.20
- ↑ "'I Go Chop Your Dollar' star arrested". Archived from the original on 16 July 2018. Retrieved 27 November 2009.
- ↑ Nkem Owoh (Osuofia) Kidnapped[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Breaking News Osuofia (Nkem Owoh) Kidnapped". Archived from the original on 2016-03-04. Retrieved 2023-09-07.
- ↑ "Jubilation in Nollywood as Osuofia is freed". Archived from the original on 19 November 2009. Retrieved 27 November 2009. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "'Scam comic' kidnapped in Nigeria". BBC News. 2009-11-10.