Nkemdilim Izuako

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Nkemdilim Izuako
Member of the United Nations Dispute Tribunal
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
2009

Nkemdilim Amelia Izuako jẹ́ adájọ́-bìnrin ti orilẹ̀-èdè Nàìjíríà. Láti ọdún 2009, ó ti wà lára ọ̀kan lára àwọn adájọ́ mẹ́ta àkọ́kọ́ ní United Nations Dispute Tribunal (UNDT).

Ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Izuako gba kẹ́kọ̀ọ́ níoa òfin, ó sì gba ìwé-ẹ̀rí ẹ̀kọ́ náà ní Obafemi Awolowo University.[1] Ó ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ ìmọ̀-òfin ní Nnamdi Azikiwe University àti Gambia Technical Institute.

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi adájọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Izuako di adájọ́ ní ọdún 1998, nígbà tí wọ́n yàn án sí ilé-ẹjọ́ ti Ipinle Anambra; wọ́n padà yàn án sí ilé-ẹjọ́ gíga ti orílẹ̀-èdè Naijiria, ó sì sìn níbẹ̀ títí di ọdún 2003. Láti ọdún 2004 wọ 2006, ó sìn gẹ́gẹ́ bíi adájọ́ ní ilẹ́-ẹjọ́ gíga àti ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ti orílẹ̀-èdè Gambia. Ní ọdún 2006, wọ́n yàn án sí High Court of Solomon Islands; òun sì ni adájọ́bìnrin àkọ́kọ́ tí wọ́n máa kọ́kọ́ yàn sí ilé-ẹjọ́ Solomon Islands.[2]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "IZUAKO, Justice Nkemdilim Amelia". Biographical Legacy and Research Foundation. 2018-08-07. Retrieved 2023-03-11. 
  2. "First female judge appointed in Solomon Islands". RNZ. 2008-06-12. Retrieved 2023-03-12.