Jump to content

Nneka Isaac Moses

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Nneka Isaac Moses jẹ́ atọ́kùn ètò orí tẹlifíṣọ̀nù ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó tún ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi aṣàpẹẹrẹ ẹ̀ṣọ́ aṣọ. Òun ni alájọdásílẹ̀ àti alákòso ètò àṣà kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Goge Africa.[1] .

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nneka lọ sí Yunifásítì ìlú Èkó láti ọdún 1987 sí 1990 níbi tí ó ti gba oyè-ẹ̀kọ́ nínu ìmọ̀ Èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Lítíréṣọ̀. Ó dá ilé-ìtajà Akenn. G Limited sílẹ̀ ní agbègbè Sùúrùlérè ní ìlú Èkó láti máa pèsè àwọn aṣọ fún ṣíṣe eré sinimá, àti fún àwọn ìpolówó ọjà lóri amóhù-máwòran.[2][3][4]

Nneka àti ọkọ rẹ̀ Isaac dìjọ dá ètò Goge Africa sílẹ̀ ní ọdún 1999, ọdún mẹ́ta lẹ́hìn ìgbeyàwó wọn. Ètò náà kọ́kọ́ jẹ́ gbígbé sáfẹ́fẹ́ ní Ọjọ́ Kínní Oṣù Kẹẹ̀wá tí n ṣe ọjọ́ ayẹyẹ òmìnira orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Àwọn ènìyàn tí wọ́n wo ètò náà lọ́jọ́ náà léní ogójì míllíọ̀nù, èyítí ó jẹ́ gbígbé sáfẹ́fẹ́ lóri àwọn ìkànnì tẹlifíṣọ̀nù bí mẹ́ẹ̀dógún. Ikọ̀ Goge Africa náà ti tẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ní ilẹ̀ Áfríkà.[5][6][7][8]

Ọ̀rọ̀ ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nneka ṣe ìgbeyàwó pẹ̀lú Isaac ní ọdún 1996. Ó bí ọmọkùnrin rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń ṣe Kamamra lẹ́hìn ọdún mẹ́tàlá tí wọ́n ti ṣe ìgbeyàwó.[9][10][11][12] Ó gba àmì-ẹ̀yẹ aṣojú àlááfíà ni ọdun 2011.[13]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Published. "Travelling with my husband has spiced up our marriage – Nneka, Goge Africa co-founder". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-27. 
  2. "Nneka &Isaac Moses: The Culture Ambassadors - Vanguard News". Vanguard News. 21 August 2013. https://www.vanguardngr.com/2013/08/nneka-isaac-moses-the-culture-ambassadors/. Retrieved 11 July 2018. 
  3. Bodunrin, Sola (24 February 2016). "I slapped my husband before agreeing to marry him – Nneka Isaac Moses". Naija.ng - Nigeria news.. Archived from the original on 11 August 2018. https://web.archive.org/web/20180811063532/https://www.naija.ng/741857-slapped-husband-agreeing-marry-nneka-isaac-moses.html#741857. Retrieved 11 July 2018. 
  4. "SPLA | Nneka Isaac Moses". www.spla.pro (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 11 July 2018. 
  5. Onen, Sunday (3 October 2017). "AMB. NNEKA ISAAC MOSES: African Travel 100 women winner". AKWAABA. Archived from the original on 12 December 2020. Retrieved 11 July 2018. 
  6. "Goge Africa | Goge Africa, Goge, Africa, Africa Independent Television, AIT :: Culture And Tourism  :: TV Programs :: Africa Independent Television - AIT". www.aitonline.tv. Retrieved 11 July 2018. 
  7. "The Princess of Goge Africa Logbaby". logbaby.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 11 July 2018. 
  8. "Ugandans love to speak like Nigerians–Nneka Isaac-Moses". Punch Newspapers. http://punchng.com/ugandans-love-speak-like-nigerians/. Retrieved 11 July 2018. 
  9. "13 years after marriage Goge Africa’s Nneka Moses delivers baby boy + ‘Real reason we named him Kamara’". Encomium. Retrieved 11 July 2018. 
  10. "Goge Africa hosts, Nneka and Isaac Moses celebrate18th wedding anniversary - Nigerian Entertainment Today". Nigerian Entertainment Today. 26 October 2015. http://thenet.ng/goge-africa-hosts-nneka-and-isaac-moses-celebrate18th-wedding-anniversary/. Retrieved 11 July 2018. 
  11. "Goge Africa’s Moses, Nneka step out with baby boy - Vanguard News". Vanguard News. 26 May 2012. https://www.vanguardngr.com/2012/05/goge-africas-moses-nneka-step-out-with-baby-boy/. Retrieved 11 July 2018. 
  12. "Goge Africa’s co host Nneka Moses gives birth after 13 years -". Channels Television. 25 February 2012. https://www.channelstv.com/2012/02/25/goge-africas-co-host-nneka-moses-gives-birth-after-13-years/. Retrieved 11 July 2018. 
  13. Onen, Sunday (3 October 2017). "AMB. NNEKA ISAAC MOSES: African Travel 100 women winner". AKWAABA. Archived from the original on 12 December 2020. Retrieved 11 July 2018.