Noni Salma

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Fáìlì:Noni Salma.jpg
Noni Salma ni Ẹbun Iwe Karun Ọdun Ẹbun Vermont

Noni Salma tí wọ́n mọ̀ tẹ́lẹ̀ sí Habeeb babatunde Lawal jẹ́ transgender, olùṣe fiimu, ònkọ̀wé, àti olùfẹ́ fiimu ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó darapọ̀ mọ́ transgender ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà níbití ọ rìnrìn àjò láti lọ kọ́ ẹ̀kọ́ gba oyè lórí fiimu ṣíṣe ní ilé-ẹ̀kọ́ fiimu tí ó wà ní ìlú New York.[1]

Ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé rẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Noni Salma gba oyè àkọ́kọ́ lórí ìmọ arti ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ìlú Èkó, níbití ó ti kọ́ nípa àwọn eré orí ìtàgé ní pàtàkì. Ó tẹ̀síwájú láti lọ kọ́ ẹ̀kọ́ nípa bí wọ́n tí ń ṣe fiimu ní ilé-ẹ̀kọ́ fiimu ti New York , èyí tí ó wà ní ìlú New York, níbití ó tí kọ́ ní pàtàkì nípa ìtọ́sọ́nà tí ó sì gba ìwé ẹ̀rí dípúlómà.[2][3]

Iṣẹ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Iṣẹ́ fiimu kúkúrú kan tí ó darí rẹ "Alibi" ni ó dára jùlọ nínú ìdíje ti "Best Crime Mystery" tí ó wáyé ní ibi ayẹyẹ fíìmù Manhattan ní ọdún 2016.[4][5] Salma gba ipò kínní nínú ayẹyẹ fíìmù ti Treasurer Cost International èyí tíí ṣe ìdíje fíìmù àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fún àmì ẹ̀yẹ tí ìwé àfọwọ́kọ fún ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ ti NYFA PhD rẹ èyí tí àkọlé rẹ ń jẹ́ "Òwúrò léhìn Àṣálẹ́". Ó ṣe àgbékalẹ̀ fíìmù kúkúrú kan èyí tí ó tún darí rẹ tí ó ń jẹ́ 'Veil of Silence' tí wọ́n tún mọ̀ sí 'Curtain of Silence', èyí tí wọ́n ṣe àfihàn rẹ nínú oṣù kẹta ọdún 2014 níbi ayẹyẹ ọdún fíìmù ti BFI Flare London LGBT ní ìlú Lọndọnu, ilẹ́ gẹ̀ẹ́sì̀; wọ́n tún ṣe àfihàn Veil Of Silence níbí ìgbìmọ̀ gbogboogbò ti àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé, Egale Canada àti ilé-iṣẹ́ Àjòjì ti Jemani pẹ̀lú àwọn ibòmíràn.[6] Ní àtẹ̀lé, wọ́n ti ṣe àfihàn Veil Of Silence ní ọ̀pọ̀ ibi àwọn ọdún ayẹyẹ fíìmù pẹ̀lú àwọn Queer Screen Film Festival, CineHomo Film Festival àti Valladolid, Spain ní oṣù kẹrin ọdún 2015, níbití ó tí gba ipò Kejì fún fíìmù ìtàn kúkúrú tí ó dára, gégé bí àwọn olùgbọ́ ti ṣe gbé oríyìn fun un. Noni Salma wà lára àkójọpọ̀ àwọn orúkọ tí wọ́n yàn fún ẹ̀bùn àwọn àmì ẹ̀yẹ ọjọ́ iwájú Áfíríkà fún àwọn olùṣètò ni oṣù 2018.[7]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Dachen, Isaac (2016-09-22). "Nigerian transgender regrets not changing his sex when he was younger". Pulse Nigeria. Retrieved 2021-09-24. 
  2. "Out, Proud and African: Noni Salma". The Rustin Times. 2019-06-17. Retrieved 2021-09-24. 
  3. "Noni Salma: ‘I Was Scared Of Living In Nigeria As A Woman In A Mans Body’". Information Nigeria. 2016-08-05. Retrieved 2021-09-24. 
  4. "Habeeb Lawal's 'Alibi' wins big at Manhattan Film Festival". PURE ENTERTAINMENT. 2016-04-27. Retrieved 2021-09-24. 
  5. Okafor, Chinedu (2018-12-02). "#NigeriasNewTribe: Davido, Ahmed Musa, Adesua Etomi, Chinwe Egwin, Samson Itodo, others make The Future Awards Africa 2018 nominees list » YNaija". YNaija. Retrieved 2021-09-24. 
  6. "News: Meet Babatunde, The Nigerian Man Who Had Surgery To Transform Into A Woman [Pictures]". Scooper. 2021-06-30. Retrieved 2021-09-24. 
  7. "Burna Boy, Adesua Etomi, Maraji others make 2018 Future Awards list". Premium Times Nigeria (in Èdè Kroatia). 2018-12-03. Retrieved 2021-09-24.