Obafemi Lasode
Ọbáfẹ́mi Lásọdé | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 4 Oṣù Kejìlá 1955 Port Harcourt, Rivers State, Nigeria. |
Orílẹ̀-èdè | Ọmọ Nigeria |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Ọmọ Nigeria |
Iṣẹ́ | olórin oǹkọ̀wé orin playwright olóòtú sinimá olùdarí sinimá |
Ìgbà iṣẹ́ | 1983– àsìkò yii |
Ọbáfẹ́mi Lásọdé Listen(tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹrin oṣù Kejìlá ọdún 4 1955) jẹ́ gbajúmọ̀ olórin, olùdarí àti olóòtú sinimá , ó jẹ́ oǹkọ̀wé àti olóòtú orin, eré-oníṣe ọmọ Nigeria.[1] Òun ni olùdarí-àgbà ilé-iṣẹ́ Even-Ezra Nigeria Limited, tí ó ṣe agbátẹrù sinimá olókìkí nì, Sango tí ó gba ọ̀pọ̀ àmì-ẹ̀yẹ lọ́dún 1997.[2][3]
Ìgbésí-ayé rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Ọbáfẹ́mi Bándélé Lásọdé lọ́jọ́ kẹrin oṣù Kejìlá ọdún 1955 ní ìlú Port Harcourt, olú-ìlú Ìpínlẹ̀ Rivers lórílẹ̀-èdè Nigeria, ṣùgbọ́n tí àwọn òbí rẹ̀ jẹ́ ọmọ bíbí Abẹ́òkúta, ní Ìpínlẹ̀ Ògùn.[4]
Ó kàwé ní St. Gregory's College ní ìlú Ọbaléndé ní Ìpínlẹ̀ Èkó, níbi tí ó ti kàwé gbàwé ẹ̀rí West African Senior School Certificate.[5] Ó tesiwaju nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ tí ó sì kàwé gbàwé ẹ̀rí Bachelor of Science nínú ìmọ̀ Business administration ní ilé ẹ̀kọ́ Kogod School of Business, ní ìlú Washington, D.C.[6] Lẹ́yìn èyí, ó tún kàwé gbàwé ẹ̀rí Master of Science nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìbánisọ̀rọ̀, Communication art láti Brooklyn College, City University of New York.[7]
Iṣẹ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ó dára pọ̀ mọ́ ilé-iṣẹ́ Inner City Broadcasting Corporation, ti ìlú New York City lọ́dún 1983 gẹ́gẹ́ bí olùdarí ìpolongo, níbi tí ó ti gba Sonny Okosuns lálejò lọ́dún 1984 ní gbajúmọ̀ gbọ̀ngán àgbáyé nì, Apollo Theater ní Harlem.[8]
Ó ṣe agbátẹrù ètò orin ilẹ̀ adúláwọ̀ Áfíríkà tí a mọ̀ sí Afrika in Vogue lórí pẹpẹ Radio Nigeria 2, ètò yìí bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1989, tí wọ́n sì ṣe é fún odidi ọdún kan gbáko.[9] In 1995, he established Afrika 'n Vogue/Even-Ezra Studios.[9]
Lọ́dún 1997, ó ṣe agbátẹrù àti olùdarí sinimá kan gbòógì tí ó gbàmì ẹ̀yẹ káàkiri ilẹ̀ adúláwọ̀ Áfíríkà tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ Sango, gbajúmọ̀ sinimá tí wọ́n yàn láti ṣíde àjọ̀dún Minneapolis–Saint Paul International Film Festival lọ́dún 2002.[10] Òun ni oǹkọ̀wé àwọn ìwé wọ̀nyí tí àkọlé wọn ń jẹ́ Television Broadcasting: The Nigerian Experience (1959–1992),[11] tí wọ́n ń lò báyìí ní àwọn ilé-ìwé ifáfitì káàkiri Nigeria.[12]
Àwọn sinimá tí ó ti kópa
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Sango (1997)
- Mask of Mulumba (1998)
- Lishabi
- Tears of Slavery
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Femi Lasode set to raise the bar with Stolen Treasures". The Sun News. 9 March 2014. Archived from the original on 18 January 2015. Retrieved 17 January 2015. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Lasode Returns to Nollywood, Builds Nigeria's First Film Village with N25million.". Starconnect Media. 26 January 2014. Archived from the original on 18 January 2015. Retrieved 18 January 2015.
- ↑ Ṣàngó in Africa and the African Diaspora. Bloomington and Indianapolis: Indiana University Press. 2009. p. 141. ISBN 978-0253220943. https://books.google.com/books?id=7tILKOSn0qYC&q=Albert+Aka-eze&pg=PA141. Retrieved 18 January 2015.
- ↑ Jonathan Haynes, ed (2000). Nigerian Video Films. Ohio University Center for International Studies. ISBN 9780896802117. https://books.google.com/books?id=OOgm9GtCzW4C&q=Sango,+the+legendary+african+King+movie+Distributor&pg=PA1. Retrieved 18 January 2015.
- ↑ "Femi Lasode speaks on SANGO The legendary Afrikan King at 10". The Nigerian Voice. 5 July 2008. Retrieved 18 January 2015.
- ↑ Afro-optimism: Perspectives on Africa's Advances. Praeger. 2003. p. 37. ISBN 9780275975869. https://books.google.com/books?id=-2wyFaU_FVkC&q=Television+broadcasting:+The+Nigerian+Experience+(1959+-+1992).&pg=PA37. Retrieved 18 January 2015.
- ↑ "Only advancement of technology can curb piracy -FEMI LASODE". nigeriatell.com. Archived from the original on 18 January 2015. Retrieved 18 January 2015.
- ↑ "About the director — Obafemi Bandele Lasode". African Film Festival New York. Retrieved 18 January 2015.
- ↑ 9.0 9.1 "Obafemi Lasode", International Contest 2000 – Artist's Page, A Song For Peace in the World.
- ↑ "Femi Lasode: Life after Sango". The Punch – Nigeria's Most Widely Read Newspaper. Archived from the original on 18 January 2015. Retrieved 18 January 2015. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Obafemi Lasode, Television Broadcasting: The Nigerian Experience (1959–1992), Caltop Publications (Nig.), 1993, ISBN 978-9783165335, at Amazon.
- ↑ Viewing African Cinema in the Twenty-First Century. Ohio University Press. 2010. p. 24. https://archive.org/details/viewingafricanci0000unse. Retrieved 18 January 2015. "Television broadcasting: The Nigerian Experience (1959–1992)."