Jump to content

Ogun wet ẹ

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ogun wet ẹ jẹ́ rògbòdìyàn ìfẹ̀hónúhàn tí ó bẹ́ sílẹ̀ láàárín nílẹ̀ Yorùbá, lápá iwọ̀-oòrùn orílẹ̀-èdè Nigeria láàárín àwọn ẹ̀yà Hausa-Fulani àti apá kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Nigerian National Democratic Party lásìkò Ètò ìdìbò olóṣèlú àkọ́kọ́ tí ó fa Ìdìtẹ̀-gbàjọba ológun àkọ́kọ́ ní Nigeria lọ́jọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kìíní ọdún 1966.[1]

"Wet" nínú gbólóhùn tí wọ́n fi sọ orúkọ ogun náà jẹ́ ọ̀rọ̀ èdè òyìnbó tí ó túmọ̀ sí kí wọ́n dáná sun àwọn olóṣèlú àti àwọn dúkìá wọn, wọ́n pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òṣèlú nígbà náà nípa dídáná sunwọ́n pa pẹ̀lú pẹ̀lú epo pẹtiróòlù lẹ́yìn tí wọ́n ti fi àgbá-ọkọ̀ síwọn lọ́rùn

Lọ́dún 1960, rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ nínú òṣèlú Nigeria, èyí ni ó fà wet ẹ níbi tí àwọn òṣèlú ti ń lo àwọn jàǹdùkú láti da ètò ìṣèlú àsìkò náà rú.[2]

Lọ́dún 1962 ni ogun wet ẹ ti wá gbòde kan nígbà tí Chief Ladoke Akintola àti Olóyè Obafemi Awolowo wọ̀yáàjà tí ó di rògbòdìyàn káàkiri ilẹ̀ Yorùbá débi pé àwọn aṣòfin ìgbà náà bẹ̀rẹ̀ sí ní bá ara wọn wọ̀jàkadì ojúkojú nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin lápá ìwọ - oòrùn Nigeria lásìkò náà.[3]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Jide Ojo (17 April 2013). "The Metamorphosis of Ibadan". The Punch. Archived from the original on 22 January 2015. https://web.archive.org/web/20150122230548/http://www.punchng.com/opinion/the-metamorphosis-of-ibadan/. Retrieved 2 August 2015. 
  2. Lawrence Chinedu Nwobu (17 August 2013). "Remi Fani-Kayode, Akintola, Awo, The Western Region And The Crisis That Truncated The First Republic". Nigeria Villagesquare. Archived from the original on 30 September 2016. Retrieved 2 August 2015. 
  3. Viviane, Saleh-Hanna (2008). Colonial Systems of Control: Criminal Justice in Nigeria. University of Otowa Press. p. 94. ISBN 9780776606668. https://books.google.com/books?id=MSXQdKh4uaIC&q=origin+of+operation+wetie&pg=PA94. Retrieved 2 August 2015.