Jump to content

Okoho

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àwòrán ọbẹ̀ Okoho (tí wọ́n sè pẹ̀lú ògúnfe àti ìgbá) èyí tí àwọn ará Idoma ní ìpínlẹ̀ Benue ní ilẹ̀ Nàìjíríà máa ń jẹ
Àwòrán ọbẹ̀ Okoho pẹ̀lú iyán (Onihi)

Okoho ni ó jẹ́ oúnjẹ ìbílẹ̀ tí a mọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Idoma ti Ìpínlẹ̀ Bẹ́núé, Àárín gbùngbùn Nàìjíríà . A sé láti ara ohun ọ̀gbìn Cissus populnea tí ó jẹ́ ọmọ ẹbí Amplidaceae.[1]

Ó jẹ́ ọbẹ̀ tí a ṣe láti ara igi Okoho eléyìí tí ó máa ń yọ̀ gidi gan-an lẹ́yìn ṣíṣè rẹ̀. Wọ́n sábàá máa ń sè é pẹ̀lú ẹran ìgbẹ́ (gẹ́gẹ́ bí ọ̀yà, àwọ̀n àti ẹran sísun àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ)ó sì máa ń jẹ́ gbígbádùn ní jíjẹ jù pẹ̀lú iyán (aka Onihi).A tún lè jẹ́ pẹ̀lú sẹ̀mó, eba (tí a ṣe láti ara gààrí) àti èlùbọ́. Wọ́n sábàá máa ń ṣe ọbẹ̀ náà láìlo epo. Òun ni oúnjẹ tí ó ní ìbọ̀wọ̀ fún jù lọ tí wọ́n sì ń bèèrè fún jù lọ ní gbogbo ayẹyẹ Idoma gẹ́gẹ́ bí ; ìgbéyàwó ìbílẹ̀, ayẹyẹ òkú ṣíṣe, ọjọ́ ìbí àti àwọn ọdún mìíràn. Ọbẹ̀ Okoho jẹ́ asaralóooore ó sì tún jẹ́ mímọ̀ fún jíjẹ́ kí oúnjẹ dà.[2] Àwọn ẹ̀yà Nàìjíríà yòókù bí Ìgbò àti Ìgalà náà tún máa ń pè é ní Okoho,[3] nígbà tí igi náà jẹ́ mímọ̀ sí Ajara tàbí Orogbolo fún ẹ̀yà Yorùbá ti àríwá àti gúsù Nàìjíríà. Àwọn Hausa sábàá máa ń pè é ní Dafara.[1]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.0 1.1 Ibrahim, H; Mdau, B B; Ahmed, A; Ilyas, M (December 30, 2010). "Anthraquinones of Cissus Populnea Guill & Perr (Amplidaceae)". African Journal of Traditional, Complementary and Alternative Medicines 8 (2): 140–143. doi:10.4314/ajtcam.v8i2.63200. PMC 3252698. PMID 22238494. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=3252698. 
  2. "How to Make Okoho Soup | cookbakingtips". cookbakingtips.com.ng. Archived from the original on 2016-08-28. Retrieved 2016-08-13.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. "Cissus Populnea & Irvingia Gabonensis : Comparative Study On Acceptability As Soup Thickner". doublegist.com. Archived from the original on 2024-04-30. Retrieved 2016-08-13.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)