Jump to content

Olapade Adeniken

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Olapade Adeniken
Medal record
Men’s Athletics
Adíje fún Nàìjíríà Nàìjíríà
Olympic Games
Fàdákà 1992 Barcelona 4x100 m relay
World Championships
Fàdákà 1997 Athens 4x100 m relay

Ọlápàdé Adeniken tí wọn bí ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù kẹjọ ọdún 1969 (19th August 1969) ní ìlú Òṣogbo) asáré fẹ̀yìntì eléré ìdárayá ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó máa sáré ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún mítà àti igba mítà. Òun ni bàbá Michael Adeniken.

Ó ti sáré gbàmìn ẹ̀yẹ bàbà nínú eré ìdíje 4 x 100 m relay pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ rẹ̀, Chidi Imoh, Oluyemi Kayode àti Davidson Ezinwa. ní ìdíje òlíḿpííkì tí Wọ́n ṣe lọ́dún 1992 ní ìlú Bacelona ní orílẹ̀ èdè Spain

Òun ni ọmọ Nàìjíríà àkọ́kọ́ tí ó sáré ìwọ̀n mítà ọgọ́rùn-ún láàárín ìṣẹ́jú-àáyá mẹ́wàá. Òun náà ló tún pa àṣeyọrí yìí rẹ́ pẹ̀lú ìṣẹ́jú-àáyá mẹ́sàn-án ó lè díẹ̀ lọ́dún 1994. Asáré díje Olusoji Fasuba (9.85 s) àti Davidson Ezinwa (9.94 s) ni ó tún peggedé jù ú lọ ní ìwọ̀n àkókò sí sáré ìwọ̀n mítà ọgọ́rùn-ún. [1]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Commonwealth All-Time Lists (Men) Archived 2007-05-20 at the Wayback Machine. - GBR Athletics