Jump to content

Ọba Ọlátẹ́rù Ọlágbègí II

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Olateru Olagbegi)

Ọba Ọlátẹ́rù Ọlágbègí II, tí wọ́n bí ní oṣù kẹjọ ọdún 1910, tí ó sìn di olóògbé lọ́dún 1998 (August 1910 - 1998) jẹ́ Ọba Ọlọ́wọ̀ ti ìlú Ọ̀wọ̀ nílẹ̀ Yorùbá, Ọ̀wọ̀ jẹ́ olú ìlú àtijó fún apá ìlà Òòrùn ilẹ̀ Yorùbá lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[1]

Wọ́n yàn án sípò Ọba ọ̀lọ́wọ̀ tìlú Ọ̀wọ̀ lọ́dún 1941, ó jọba fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n gbáko kí Wọ́n tórọ̀ ọ́ loyè nítorí ìjà òṣèlú láàárín Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ àti Samuel Ládòkè Akíntọ́lá tí ẹgbẹ́ òṣèlú Action Group. Ó lọ sìmgbà lẹ́yìn náà lẹ́yìn odi láti ìgbà náà. [citation needed]Ààfin rẹ̀ ni Awólọ́wọ̀ àti àwọn sọ̀ǹgbè rẹ̀ tí dá ẹgbẹ́ òṣèlú Action Group sílẹ̀ lọ́dún 1950, ṣùgbọ́n nígbà tí ìjà náà bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1960, Ọba Ọlátẹ́rù gbé lẹ́yìn Akíntọ́lá.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé fífi í jọba fa èhónú láàárín ìlú, ṣùgbọ́n wọ́n kòrí I rọ̀ lóyè àfi ìgbà tí àwọn ológun gba ìjọba lọ́dún 1966,ànfàní yìí ni àwọn ará ìlú kan lò nígbà náà láti gbé á wojú rẹ̀, tí wọn sìn dá wàhálà sílẹ̀ ní ìlú, nítorí wàhálà yìí ni ìjọba ológun ìgbà náà fi rọ̀ ọ́ lóyè, tí Wọ́n sìn lé e kúrò ní ìlú lọ́dún 1966. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, Wọ́n tún fi í sípò ọba padà nílùú Ọ̀wọ̀.

Wọ́n dá padà sípò ọba lọ́dún 1993 nígbà tí ọba tí ó jẹ lẹ́yìn rẹ̀ wàjà.[2][3]

Wọ́n dá a lọ́lá lọ́jọ́ ibi Ààrẹbìnrin tí orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún. [4]

Ọba Ọlátẹ́rù wàjà lọ́dún 1998,ọmọ rẹ̀,Fọlágbadé Ọlátẹ́rù Ọlágbẹ́gi III ní o sìn gorí ìtẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà náà.

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Robin Poynor, 'Naturalism and Abstraction in Owo Masks', African Arts, Vol. 20, No. 4 (Aug., 1987)
  2. Bamidele Johnson, "Exit Of A Two-Time Monarch," Tempo. November 12, 1998
  3. Bamidele Adebayo, "Bloody Throne," The News (Lagos). September 27, 1999
  4. London Gazette http://www.london-gazette.co.uk/issues/42051/supplements/3974