Olufemi Bamiro

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Olufemi Adebisi Bamiro je Ojogbon ninu imo-ero sayensi o si je Oga-Agba ana fun ile Eko Giga Fasiti ti ilu Ibadan[1][2][3][4]

Ibere Igbe Aye ati eko[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bi Olufemi ni ojo kerin-din-logun osu Kesan odun 1947 ni ilu Ijebu-Igbo, Ipinle Ogun. O lo si ile iwe girama Molusi ni Ijebu-lgbo ati ile iwe girama ti Ijoba ni ilu Ibadan, oun ni o si ni esi idanwo ti o dara julo ninu idanwo ti eko girama ti o tun ga si ti a se'to re lati owo Cambridge fun odun, 1967. Leyin eyi, o tesiwaju gegebi akeko Shell lo si ile eko giga Nottingham, ni ilu Nottingham, orile-ede Geesi, nibi ti o ti keko gb'oye imo ijinle sayensi ninu imo ero sayensi pelu aseyori ipele ti o ga julo ni odun 1971. O sise fun igba die pelu ile ise Shell-BP ni ilu Naijiria gegebi onimo nipa opa epo ki o to lo si ile eko giga McGill, ni ilu Montreal, ni orile-ede Kanada labe eto eko ofe alafowosowopo gbogboogbo ti ilu Kanada nibi ti o ti gba oye Omowe ni odun 1975 leyin odun meji ati aabo. O pada si orile-ede Naijiria nibi ti o ti bere ise olukoni ni ile eko giga Fasiti ti ilu Ibadan ni odun 1975 o si tesiwaju titi o fi di Ojogbon akoko ninu imo ero sayensi ni ile eko giga naa ni odun 1983. O je ogbontarigi akose-mo-se lori awon oro ti o je mo sayensi ati imo ero, eko giga, ise asela ati imo nipa oniruru imo.  O ti ko opolopo iwe lori imo sayensi ati imo ero ninu awon iwe apileko ni orile ede yi ati ni awon orile ede agbaye ti o ku.[5][6]

Awon itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]