Olusola Momoh
Olusola Momoh | |
---|---|
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ẹ̀kọ́ | University of Lagos, Harvard Business School |
Iṣẹ́ | Media executive, Journalist |
Ìgbà iṣẹ́ | 42 Years |
Organization | Channels Television |
Olólùfẹ́ | John Momoh |
Àwọn ọmọ | Three |
Olúṣọlá Momoh jẹ́ adarí àwọn ilé íròyìn kan ní Nàìjíríà.[1] Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùdásílẹ̀ àti Igbákejì Alága ti Àwọn Channels Media Group, ilé-iṣẹ́ tí ó ń darí Channels TV. Momoh gboyè B.Sc ní Mass Communicatio láti Yunifásitì ìlú Èkó. Ó tún gba àmì ẹyẹ pí polongo ìròyìn ní Yunifásitì ìlú Èkó.[2]
Ní ọdún 2014, Ó wà lára àwọn women leadership forum program ti ilé-ìwé ìsòwò Harvard.[3]
Iṣẹ́-ṣíṣe
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ṣáájú kí ó tó dá Channel Television àti Channels Media Group silẹ̀, Momoh jẹ́ oníròyìn pẹ̀lú Nigeria Television Authority(NTA), láàrin ọdún 1979 sí 1987. Ní àkókò yìí, ó ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àgbéjáde lórí bí Nàìjíríà ṣe ń sọ epo nù.[4]
Yàtò sí isẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi akàròyìn, Momoh ṣiṣẹ́ fún ọdún méje ní àwọn ilé-ìfowópamọ́. Ó ṣiṣẹ́ ní International Merchant Bank (IMB).[5]
Àwọn àmì ẹyẹ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọdún 2019, Momoh gbà Àmì-ẹ̀yẹ Doctorate degree nínú ìṣàkóso ìṣòwò ní Yunifásitì Achievers, ọ̀wọ̀, Ìpínlẹ̀ Oǹdó.[6] Ní Oṣù Kọkànlá ọdún 2021, àjọ Women in Management, Business and Public Service (WIMBIZ) ká mọ́ ọkàn lára àwọn obìnrin tí ó lókìkí jù. Àjọ náà tún ká mọ́ ọkàn nínú àwọn obìnrin tí ó lókìkí jù nínú àwọn oníròyìn obìnrin ní Nàìjíríà.[7]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Executive Vice-Chairman – Channels Television". Retrieved 2021-11-23.
- ↑ Admin (2020-07-01). "MOMOH, Olusola". Biographical Legacy and Research Foundation (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-11-23.
- ↑ "Executive Vice-Chairman – Channels Television". Retrieved 2021-11-23.
- ↑ "Mrs. Olusola Momoh". The Aart of Life Foundation (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-11-23.
- ↑ "Biography of Olusola Momoh, Vice-Chairman, Channels Television.". biography.hi7.co. Retrieved 2021-11-23.
- ↑ "Ijeoma Nwogwugwu, Stella Din, Kadaria Ahmed named among 25 most powerful Nigerian female journalists". TheCable (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-10-02. Retrieved 2021-11-23.
- ↑ "Ijeoma Nwogwugwu, Stella Din, Kadaria Ahmed named among 25 most powerful Nigerian female journalists". TheCable (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-10-02. Retrieved 2021-11-23.