Owe Yoruba
Òwe ni ohùn ìjìnlẹ̀ ẹnu àwọn àgbà-gbà ní ilẹ̀ Yorùbá tí ó kun fún ọgbọ́n, ìmọ̀, ìṣítí, ìkìlọ̀, àti òye àwọn bàbá ńlá baba wa ní ilé káàrọ̀-o-kò- jíire. Àwọn àgbà-gbà Yorùbá ma ń ṣe àmúlò òwe láti lè sọ́ra fún àsọjù tàbí àsọdùn ọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n bá wà ní àwùjọ tàbí wọ́n ń tàkurọ̀sọ pẹ̀lú ẹlòmíràn. Ọmọ Yorùbá tí kò bá mọ bí a tí ń lo òwe ti pàdánù ọ̀ṣọ́ kan tí ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú èdè rẹ̀. [1]
Ìsọ̀rí òwe
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Oríṣiríṣi ni òwe Yorùbá pín sí, Yorùbá Ma ń sábà lo òwe fún orisirisi nkan nínú ìgbésí ayé wọn. Àwọn ọ̀nà tí òwe Yorùbá pín sí ni:
Òwe Ìkìlọ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Òwe yí ni wọ́n ma ń ló láti kìlọ̀ ìwà pàá pàá jùlọ ìwà ẹ̀gbin àti ìbàjẹ́ fún ènìyàn. Àpẹẹrẹ irú rẹ̀ ni:
- Diẹ̀ diẹ̀ ni imú ẹlẹ́dẹ̀ ń wọ'gbà
- Awí fúni kí ó tó dáni, àgbà ìjàkadì ni
- Ìgbà kò lọ bí òréré, ayé kò tọ́ lọ bí ọ̀pá ìbọn
- Bí a bá sọ̀kò sọ́jà, ará ilé ẹni ní ń bá
- Kèrègbè tó fọ́, dẹ̀yìn lẹ́yìn odò.
- Ohun tí o ń wá nídí akọṣu, wà á kàn án nídí ewùrà.
Òwe Ẹ̀kọ́-ilé
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Yorùbá ma ń fi òwe yí kọ́ àwọn ọmọ wọ́n bí wọ́n tile ṣojú àwọn òbí wọn ati bí wọ́n ṣe lè hùwà láwùjọ. Àpẹẹrẹ irúfẹ́ òwee bẹ́ẹ̀ ni:
- Ilé là á'wò kí a tó sọmọ lórúkọ
- Bílé bá sani bí kò sani, àwọ̀ la tí ń mọ̀.
- Ilé ẹni la ti ń jèkúté onídodo
- Agùtan tó bájá rìn, yóò jẹ̀gbẹ́
- Yára gbọ́rọ̀, lọ́ra fèsì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Òwe ìmọ̀ran
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n ma ń fi òwe yí lani lọ́yẹ̀ tàbí gbani níyànjú lórí àwọn ọrọ̀ tó bá ta kókó. Àpẹẹrẹ rẹ̀ ni:
- Bí ó bá kọjú sí ọ kò o ta, bí ó bá kọ̀yìn sí ọ kí o ta, bí ó bá ku ìwọ nìkan; kí o tún èrò rẹ pa.
- Bíṣu ẹni bá ta , Ààrẹ dawọ́ bòó jẹ ni àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Àwọn itọ́ka sí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Owe Yoruba: 100 Yoruba Proverbs & Their Meanings". Nigerian Finder. 2019-10-05. Retrieved 2021-05-30.