Jump to content

Oyin

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
A jar of honey with a honey dipper and an American biscuit

Oyin ni ó jẹ́ ohun àdídùn olómi tí ìrísí rẹ̀ kìí ṣàn bí omi tí àwọn kòkòrò oyin oríṣiríṣi ma ń pèsè.[1][2] Kòkòrò oyin ni wọ́n ma ń kórajọ pọ̀ tí wọ́n ma ń ya orísiríṣi oje tí wón bá rí fà mu lára orísiríṣi ọ̀mùnú ewé òdòdó àti igi tí wọ́n bá ti mu. Àwọn ohun tínwón ti fàmu yìí ni wọ́n ma ń pọ̀ jáde láti ẹnu wọn padà sínú ilé wọn tí wọ́n ń pe ní afárá oyin.

Afárá oyin ni ó ní ojú ihò tí ó lé ní ẹgbẹ̀rún, bákan náà ni àwọn irúfẹ́ kòkòrò oyin mìíràn tún ma ń pèsè oyin tiwọn sínú afárá tí wọ́n ti ṣe lọ́jò sínú ìkòkò.[1][2][3]

Oyin ni ó wúlò púpọ̀ fún ìlò ọmọnìyàn lẹ́yìn tí àwọn kòkòrò oyin bá ti pèsè rẹ̀ tán sínú afárá ni àwọn ènìyàn ma ń lọ fà oyin. [4]

Bákan náà ni àwọn ènìyàn tún ma ń si oyin tí àwọn onímọ̀ nípa iṣẹ́ yìí sì ń pèé ní beekeeping tàbí apiculture.

Dídùn oyin àti ànfàní rẹ̀ fún ìlera

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Oyin ma ń dùn látàrí èròjà àdídùn bí ṣúgà tí ó jẹ́ àdámọ́ tí ó wà nínú rẹ̀. Adùn inú rẹ̀ ń ṣe déédé pẹ̀lú àádùn tí ó wà nínú ṣúgà oníhóró tàbí ṣúgà oníyẹ̀fun.[5][6] Ẹ̀kún ṣíbí ìmùkọ kan (15 mL) ni yóò fún wa ní okún 190 kilojoules (46 kilocalories) tí óunjẹ afúnilókun yóò fún wa.[7] Bákan náà ni wón lè po oyin mọ́ ìyẹ̀fun tí wọ́n fi ń ṣe búrẹ́dì àti àwọn mìíran bẹ́ẹ̀. Bákan náà ni ó ní òórùn àdídùn afani-mọ́ra nígbà tí a bá lòó dípò àwọn èròjà amónjẹ-dùn. Oyin kìí bàjẹ́ tàbí gbe kalẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́ tàbí [5] Wọ́n fìdí èyí múlẹ̀ látara oyin kan tí àwọn aláwàárí inú ilẹ̀ rí lẹ́yìn ẹgbẹ̀rún ọdún tí kò sì yí pada láwọ̀ àti ládùn pẹ̀lú.[8][9]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.0 1.1 Crane, Eva (1990). "Honey from honeybees and other insects". Ethology Ecology & Evolution 3 (sup1): 100–105. doi:10.1080/03949370.1991.10721919. ISSN 0394-9370. 
  2. 2.0 2.1 Grüter, Christoph (2020). Stingless Bees: Their Behaviour, Ecology and Evolution. Fascinating Life Sciences. Springer New York. doi:10.1007/978-3-030-60090-7. ISBN 978-3-030-60089-1. https://link.springer.com/book/10.1007%2F978-3-030-60090-7#toc. Retrieved 27 May 2021. 
  3. Àdàkọ:Bulleted list
  4. Crane, Ethel Eva (1999). The World History of Beekeeping and Honey Hunting. Routledge. ISBN 978-1-136-74670-3. 
  5. 5.0 5.1 National Honey Board. "Carbohydrates and the Sweetness of Honey" Archived 1 July 2011 at the Wayback Machine.. Last accessed 1 June 2012.
  6. Oregon State University "What is the relative sweetness of different sugars and sugar substitutes?". Retrieved 1 June 2012.
  7. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named Nutrient Data
  8. Geiling, Natasha (22 August 2013). "The Science Behind Honey's Eternal Shelf Life". Smithsonian. https://www.smithsonianmag.com/science-nature/the-science-behind-honeys-eternal-shelf-life-1218690/?no-ist. 
  9. Prescott, Lansing; Harley, John P.; Klein, Donald A. (1999). Microbiology. Boston: WCB/McGraw-Hill. ISBN 978-0-697-35439-6. https://archive.org/details/microbiology00pres.