Jump to content

Oyinkánsọ́lá Àbáyọ̀mí

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Oyinkánsọ́lá Àbáyọ̀mí
Fáìlì:Oyinkansola Abayomi.jpg
Oyinkansola, Lady Abayomi
Ọjọ́ìbíOyinkánsọ́lá Àjàsá
(1897-03-06)6 Oṣù Kẹta 1897[1]
Èkó, Nàìjíríà (tí ó jẹ́ olú-ìlú ìṣẹ̀ìjọba amúnisìn orílẹ̀-èdè Bìrìtìkó)[1]
Aláìsí19 March 1990(1990-03-19) (ọmọ ọdún 93)[1]
Èkó, Nigeria[1]
Orílẹ̀-èdèỌmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Orúkọ mírànOyinkán
Iṣẹ́Aṣègbèfábo, Okuki, Scouting guide
Gbajúmọ̀ fúnGirl Guides

Olóyè Oyinkánsọ́lá Àbáyọ̀mí, ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí "Oyínkán" ni wọ́n bí lọ́jọ́ kẹfà oṣù kẹta ọdún 1897, tí ó sìn kú lọ́jọ́ kẹsàn-án oṣù kẹta ọdún 1990 jẹ́ ajàjàòmìnira àti Aṣègbèfábo ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni adarí ẹgbẹ́ obìnrin, Girl Guides àti oludásílẹ̀ ẹgbẹ́-òṣèlú àwọn obìnrin, Nigerian Women's Party, NWP.

Ìgbà èwe àti ìkẹ́kọ̀ọ́ tẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí ó gẹ́gẹ́ bí Oyínkánsọ́lá Àjàsá lọ́dún 1897 ló rílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[2] Àwọn òbí rẹ̀ ló máa ń pè é ní Oyínkán, èyí tí ó jẹ́ àpèkúrú orúkọ rẹ̀. Ó ní àbúrò ọkùnrin kan tí ó ń jẹ́ Akéúṣọlá. Èyí yìí kú nígbà tí ó wà lọ́mọdún méjì. [1] Orúkọ bàbá rẹ̀ ni Kítóyè Àjàsá, ọmọ bibi Yorùbá pọ́nńbélé, ẹni tí ìsèjọba Bìrìtìkó kọ́kọ́ fi joyè alàgbà ìjọ. Ìyá rẹ̀ ni Lucretia Ọláyíninká Moore, ọmọbabìnrin ìlú Ẹ̀gbá.[3] Ó jẹ́ ìbátan Kofo Ademola. Ó kàwé ní ilé-ìwé àwọn obìnrin, Anglican Girls' Seminary ní ìlú Èkó lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Bákan náà, ó kàwé gboyè lọ́dún 1909 ní ilé-ìwé Young Ladies Academy ní Ryford Hall, tí ó wà ní Gloucestershire,ní orílẹ̀-èdè Ilẹ̀gẹ̀ẹ́sì. Lọ́dún 1917, ó kàwé ní Royal Academy of Music ní ìlú London. Ó padà sí Èkó lọ́dún 1920. Ó Ṣe iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ ìmọ̀ orin ní Anglican Girls' Seminary. Ní àkókò yìí ni ó pàdé ọkọ rẹ̀, tí orúkọ rẹ̀, amọ̀fin Morónfólú Àbáyọ̀mí tí wọ́n sìn fẹ́ ara wọn lọ́dún 1923. They married in August 1923, tí wọ́n yóò pa nílé ẹjọ́ lẹ́yìn oṣù méjì sí ìgbà náà.[1]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 1.5 Martin, Christa (2002). Abayomi, Oyinkansola (1897–1990). Farmington Hills: Gale Research, Inc.. Archived from the original on 2013-05-18. https://web.archive.org/web/20130518160528/http://www.highbeam.com/doc/1G2-2591300043.html. Retrieved 2020-11-02. Àdàkọ:Subscription
  2. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named oxford
  3. Ruth Roach Pierson; Nupur Chaudhuri; Beth McAuley (1998). Nation, Empire, Colony: Historicizing Gender and Race. Indiana University Press. pp. 87–88. ISBN 978-0-253-21191-0. https://books.google.com/books?id=kO8yRHeDxVcC&pg=PA93. Retrieved 29 December 2012.