Jump to content

Pẹ̀lẹ́

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Pele

Mo kí ìyáálé ilé kan pẹ̀lú ọ̀wọ̀ níjọ́sí,

Mo ní ‘Ẹ pẹ̀lẹ́, mà~’

Ó bá bínú, ó ní, ‘Mo jẹ́gbẹ́ ẹ kọ́ bùọ̀dá,

Tó fi ń ṣe mí ní. “Ẹ pẹ̀lẹ́ mà.”

Ó ṣe mí ní kàyééfi mo bẹ̀bẹ̀ gán-ín.

Mo ní, ‘Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má mà bínú,

Tinútinú ni mo fi kí i yín kú akitiyan.’

Èyí wá mú mi rántí ọ̀rọ̀ àwọn àgbà, ...

Irahun aja kan

Aja

Irahun

Ìgbà tí mo kọ́kọ́ fojú bale ayé,

Mo gbà, ẹ ẹ̀ pọ́n mi lójú kankan.

Ẹ̀ ń kẹ́ mi, ẹ̀ ń gẹ̀ mí.

Ẹ ẹ̀ sì ṣàìfúnmi lóúnjẹ.

Àgàgà tẹ́ ẹ tún rámì akọ nísàlẹ̀,

Bí i ká jẹ̀kọ ìdájí ni.

Níjọ́ eegun ẹran lásán,

Níjọ́ apẹ híha jẹ. ...

Agbéraga, Lọ̀ ọ́ Ṣe Wọ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A ti rẹ́ni tó gungi dé téńté tí ò jábọ́.

A tí réèyàn tó mòòkùn ọ̀sẹ̀ tí ò sì rì.

A ti rẹ́ni tó jẹgba aáyán láìpòkóló.

A ti réèyàn tó gbọ́kùnrùn mì láìbì.

A ti ródó ìrókò, a ti ródó idẹ.

Àyàfi ká tòkè múlé mọ wálẹ̀. ...

Ọ̀nà Ọpẹ́ Pọ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n pọ̀ lẹ́nu Yorùbá.

Ọmọ Oòduà ló ni ká-sọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀.

Wọ́n ti pàṣamọ̀ àìmọnú-ún-rò ọmọ adáríhurun

Gẹ́gẹ́ bí okùnfà àìmọpẹ́-ẹ́-dú.

Béèyàn ò sì wáá mọ inú ún rò,

Tó ṣe pé torí ẹ̀ ni ò jẹ́ ó mọpẹ́ẹ́ dú,

Ṣebí ó lójú ti fi ń ríran. ...

Olúgbóyèga Àlàbá

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Olúgbóyèga Àlàbá ní ìlú Ìgàngàn ní ìwọ̀n àádọ́ta ọdún síwájú àkókò yìí.

Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti Ìjọ Elétò àti ilé-ẹ̀kọ́ mọdá ti Ìjọ yìí kan náà ní ìlú Ìgàngàn. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Olùkọ́ni Leo Mímọ́ ti Ìjọ Àgùdà ní ìlú Abẹ́òkúta. Ó tún lọ sí Yunifásítì ti Èkó ní Akọkà....

Jìbìtì Dọ̀gá Ìṣekúṣe

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

‘Ẹni a bá ní a ó jọ

Jíjù là á jù ú!’

Jìbìtì jọ Ìṣekúṣe

Ṣé níjọ́ tí ìṣekúṣe ń bọ̀ wálé ayé,

Ìjọ Jìbìtì kúkú ni.

Ẹni ńlá ni, kì í nìkan rìn.

Nígbà Ìṣekúṣe dáyé tán,

Ó gbé e lé Jìbìtì lọ́wọ́. ...


Ọlátúnjí Ọ̀pádọ̀tun (2005); Àwọn Akéwì Ṣàṣàrò University Press PLC. ISBN 978-030-741-9, oju-iwe 20-35.

Olatunji Opadotun

link title Archived 2007-08-07 at the Wayback Machine.