Pẹ̀lẹ́
Pẹ̀lẹ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Mo kí ìyáálé ilé kan pẹ̀lú ọ̀wọ̀ níjọ́sí,
Mo ní ‘Ẹ pẹ̀lẹ́, mà~’
Ó bá bínú, ó ní, ‘Mo jẹ́gbẹ́ ẹ kọ́ bùọ̀dá,
Tó fi ń ṣe mí ní. “Ẹ pẹ̀lẹ́ mà.”
Ó ṣe mí ní kàyééfi mo bẹ̀bẹ̀ gán-ín.
Mo ní, ‘Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má mà bínú,
Tinútinú ni mo fi kí i yín kú akitiyan.’
Èyí wá mú mi rántí ọ̀rọ̀ àwọn àgbà, ...
Ìráhùn Àjá Kan
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìgbà tí mo kọ́kọ́ fojú bale ayé,
Mo gbà, ẹ ẹ̀ pọ́n mi lójú kankan.
Ẹ̀ ń kẹ́ mi, ẹ̀ ń gẹ̀ mí.
Ẹ ẹ̀ sì ṣàìfúnmi lóúnjẹ.
Àgàgà tẹ́ ẹ tún rámì akọ nísàlẹ̀,
Bí i ká jẹ̀kọ ìdájí ni.
Níjọ́ eegun ẹran lásán,
Níjọ́ apẹ híha jẹ. ...
Agbéraga, Lọ̀ ọ́ Ṣe Wọ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]A ti rẹ́ni tó gungi dé téńté tí ò jábọ́.
A tí réèyàn tó mòòkùn ọ̀sẹ̀ tí ò sì rì.
A ti rẹ́ni tó jẹgba aáyán láìpòkóló.
A ti réèyàn tó gbọ́kùnrùn mì láìbì.
A ti ródó ìrókò, a ti ródó idẹ.
Àyàfi ká tòkè múlé mọ wálẹ̀. ...
Ọ̀nà Ọpẹ́ Pọ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n pọ̀ lẹ́nu Yorùbá.
Ọmọ Oòduà ló ni ká-sọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀.
Wọ́n ti pàṣamọ̀ àìmọnú-ún-rò ọmọ adáríhurun
Gẹ́gẹ́ bí okùnfà àìmọpẹ́-ẹ́-dú.
Béèyàn ò sì wáá mọ inú ún rò,
Tó ṣe pé torí ẹ̀ ni ò jẹ́ ó mọpẹ́ẹ́ dú,
Ṣebí ó lójú ti fi ń ríran. ...
Olúgbóyèga Àlàbá
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]A bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Olúgbóyèga Àlàbá ní ìlú Ìgàngàn ní ìwọ̀n àádọ́ta ọdún síwájú àkókò yìí.
Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti Ìjọ Elétò àti ilé-ẹ̀kọ́ mọdá ti Ìjọ yìí kan náà ní ìlú Ìgàngàn. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Olùkọ́ni Leo Mímọ́ ti Ìjọ Àgùdà ní ìlú Abẹ́òkúta. Ó tún lọ sí Yunifásítì ti Èkó ní Akọkà....
Jìbìtì Dọ̀gá Ìṣekúṣe
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]‘Ẹni a bá ní a ó jọ
Jíjù là á jù ú!’
Jìbìtì jọ Ìṣekúṣe
Ṣé níjọ́ tí ìṣekúṣe ń bọ̀ wálé ayé,
Ìjọ Jìbìtì kúkú ni.
Ẹni ńlá ni, kì í nìkan rìn.
Nígbà Ìṣekúṣe dáyé tán,
Ó gbé e lé Jìbìtì lọ́wọ́. ...
Iwe ti a yewo
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]link title Archived 2007-08-07 at the Wayback Machine.