Pepper soup
Pepper soup jẹ́ ọbẹ̀ láti Nàìjíríà, tí a sè nípa lílo orísìírísìí ẹran tàbí ẹja, ata gígún, iyọ̀, efinrin àti calabash nutmeg gẹ́gẹ́ bí ohun èlò tí ó ṣe pàtàkì. Ó jẹ́ ọbẹ̀ tí ó ta tí ó ní ìrísí tí ó fúyẹ́, tí ó sì lómi. Pẹ̀lú orúkọ rẹ̀, ọbẹ̀ náà kì í ṣe èyí tí ó gbọ́dọ̀ ta, èyí tí ó túmọ̀ sí, adùn rẹ̀ le gidi gan-an, pẹ̀lú líle, kíkorò, igi, àti adùn, àti pẹ̀lú níní ọwọ́rọ́.[1] Wọ́n gbà pé ó jẹ́ oúnjẹ fún àwọn kan ní Western Africa, àti díẹ̀ nínú àwọn Ìwọ-Oòrùn ilẹ̀ Áfíríkà gbàgbọ́ pé ọbẹ̀ náà ní egbòogi nínú.
Àgbéyẹ̀wò
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Pepper soup jẹ́ ọbẹ̀ tó wọ́pọ̀ ní Nàìjíríà tí ó jẹ́ ṣíṣè nípa lílo orísìírísìí ẹran, ẹja, ata àti calabash nutmeg gẹ́gẹ́ bí ohun èlò pàtàkì.[2] [3] Pepper soup ta gidi gan-an[4] ó dẹ̀ máa ń lọ dáadáa pẹ̀lú ọtí tútù tàbí ọtí ẹlẹ́rìndùndùn. Nígbà tí wọ́n bá sè é gẹ́gẹ́ bí ní àpéjọ pàtàkì, pepper soup gbajúmọ̀ dáadáa ní Pub. Ní Nàìjíríà, wọ́n máa ń jẹ ẹ́ ní "ààyè ìgbádùn" gẹ́gẹ́ bí ìgbafẹ́ tàbí oúnjẹ " ní ìmọ̀sílára gidi ".[5] Pepper soup cubes, èyí tí a pò pọ̀ mọ́ ata tí a lò nínú pepper soup, ni ilé-iṣẹ́ kan ní Nàìjíríà ń ṣe àgbéjáde rẹ̀.
Àpèjúwe
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Pepper soup jẹ́ ọbẹ̀ olómi.[6] Ó lè di ṣíṣè pẹ̀lú àpapọ̀ orísìírísìí ẹran,[7] bí ẹja, edé, ṣàkì, inú ẹ̀ran, ẹran adìẹ, ewúrẹ́,[8][9] [10] [11] ẹran tàbí awọ màlúù. Àwọn ohun èlò tí a tún lè fi kún un ni tomatoes, àlùbọ́sà aláwọ̀ ewé, ata wẹẹrẹ, kànáfùrú, cinnamon àti òrom̀bó.[12] Fufu, oúnjẹ tí a sè láti ara ẹ̀gẹ́ ṣíṣè àti gígún cassava tàbí àwọn túbà mìíràn,máa ń di lílò nígbà mìíràn gẹ́gẹ́ bí ohun èlò, èyí tí ó máa ń mú ọbẹ̀ náà ki tí ó sì máa ń jẹ́ kí ó ìrísí kíki. Nígbà mìíràn, wọ́n máa ń jẹ ẹ́ pẹ̀lú àwọn oúnjẹ mìíràn bi ìrẹsì tàbí iṣu ṣíṣè, tàbí jíjẹ pẹ̀lú àwọn ohun èròjà yìí. Ní Ìwọ-Oòrùn ilẹ̀ Áfíríkà, ìta ni wọ́n ti máa ń sè é nínú cauldron.
Pepper soup ni wọ́n gbà pé ó jẹ́ oúnjẹ láàárín àwọn ènìyàn riverine ní Nàìjíríà. Ó jẹ́ ọbẹ̀ tó gbajúmọ̀ ní Nàìjíríà (agbègbè ìwọ oòrùn ), àti àwọn ìlú mìíràn tí wọ́n ti ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní ìwọ oòrùn Áfíríkà. Awọn èèyàn ilẹ̀ Ìwọ-Oòrùn Áfíríkà kan gbàgbọ́ pé ọbẹ̀ adìẹ pepper soup ní iye egbòogi, tí ó sì máa ń wo àwọn aláìsàn sàn. Pepper soup nígbà mìíràn tún máa ń di jíjẹ fún àwọn obìnrin tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ, nítorí pé àwọn kan gbàgbọ́ pé ó máa ń ṣe ìrànwọ́ fún jínjinná ara lápapọ̀ àti yíyọ omi ti Ọmú.[13] Ó sábàá máa ń di jíjẹ lẹ́yìn ayẹyẹ ìgbéyàwó, fún ọ̀nà láti dá okun ara padà.
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Nigerian Pepper Soup". Serious Eats (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-23.
- ↑ McWilliams, J.E. (2005). A Revolution in Eating: How the Quest for Food Shaped America. Arts and Traditions of the Table: Perspectives on Culinary History Series. Columbia University Press. p. 33. ISBN 978-0-231-12992-3. https://books.google.com/books?id=mcDVbt86uSYC&pg=PA33.
- ↑ Eko Magazine. Newswatch Communications Limited. 1992. p. 3. https://books.google.com/books?id=dlXhAAAAMAAJ&q=Pepper+Soup,+delicacy.
- ↑ Kallon, Z.K. (2004). Zainabu's African Cookbook: With Food and Stories. Citadel Press. p. 54. ISBN 978-0-8065-2549-5. https://books.google.com/books?id=aOa64BA21m8C&pg=PA54.
- ↑ Harris, J.B. (1998). The Africa Cookbook: Tastes of a Continent. Simon & Schuster. p. 124. ISBN 978-0-684-80275-6. https://archive.org/details/africacookbookta0000harr.
- ↑ Long, L.M. (2016). Ethnic American Cooking: Recipes for Living in a New World. Rowman & Littlefield Publishers. p. 168. ISBN 978-1-4422-6734-3. https://books.google.com/books?id=HTWNDAAAQBAJ&pg=PA168.
- ↑ Olarewaju, Olamide (October 12, 2015). "DIY Recipes: Easy way to make Nigerian peppersoup". Pulse Nigeria. Archived from the original on May 20, 2017. Retrieved September 11, 2016.
- ↑ "Pepper Soup". The Congo Cookbook. April 11, 2013. Retrieved September 11, 2016.
- ↑ Massaquoi, R.C.J. (2011). Foods of Sierra Leone and Other West African Countries: A Cookbook. AuthorHouse. p. 22. ISBN 978-1-4490-8154-6. https://books.google.com/books?id=bKwN7Absx6AC&pg=PA22.
- ↑ Megill, E.L. (2004). Sierra Leone Remembered. AuthorHouse. p. 36. ISBN 978-1-4184-5549-1. https://books.google.com/books?id=tw-RlOWNUjwC&pg=PA36.
- ↑ Asika-Enahoro, C. (2004). A Slice of Africa: Exotic West African Cuisines. iUniverse. p. 17. ISBN 978-0-595-30528-5. https://books.google.com/books?id=ddL44UDqyu8C&pg=PA17.
- ↑ Montgomery, B.V.; Nabwire, C. (2001). Cooking the West African Way: Revised and Expanded to Include New Low-fat and Vegetarian Recipes. Easy Menu Ethnic Cookbooks 2nd Edition. Ebsco Publishing. p. 51. ISBN 978-0-8225-0570-9. https://books.google.com/books?id=PAL3hEQJVkkC&pg=PA51.
- ↑ Webb, L.S. (2000). Multicultural Cookbook of Life-Cycle Celebrations. Cookbooks for Students Series. Oryx Press. p. 69. ISBN 978-1-57356-290-4. https://archive.org/details/multiculturalcoo00lois.