Princess Shyngle
Princess Shyngle | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Princess Shyngle 25 Oṣù Kejìlá 1990 Banjul, Gambia |
Iṣẹ́ | Actress, producer |
Ìgbà iṣẹ́ | 2011–present |
Princess Shyngle tí wọ́n bí ní ọjọ́ karùnlélógún oṣù Kejìlá ọdún 1990, jẹ́ òṣèré àti adarí eré ní orílẹ̀-èdè Gámbíà .[1]
Ìgbésí ayé ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àti Ẹ̀kọ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Princess Shyngle jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Gámbíà. Bàbá ẹ̀, Winston Shyngle, jẹ́ ìgbákejì gíwá ní orílẹ̀-èdè Gámbíà ìyá ẹ̀ sì jẹ́ olówò ọrọ̀ ajé. Ó ká ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama ní Gámbíà orílẹ̀-èdè kékere kan ní Ìwọòrùn Áfríkà.[1]
Iṣẹ́ Òṣèré
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Lẹ́yìn tí ó jẹ ẹ̀bùn ipò kẹta ní Next Movie Star Africa competition, Princess Shyngle ti ṣe oríṣìíríṣìí eré àwòrán mìíràn pàápàá ní orílẹ̀-èdè Gánà. rincess Shyngle jẹ́ ara àwọn ènìyàn tí wọ́n yàn fún àmì ẹ̀yẹ "the discovery of the year" ní 2015 Ghana Movie Awards. Ó ti wà nínú àwọn eré tí àwọn gbajúmọ̀ òṣèré mìíràn bíi Juliet Ibrahim, John Dumelo, Martha Ankomah, àti D-Black wà.[2] Àwọn iṣẹ́ tí ó ṣe tó gbajúmọ̀ jù ni Why Do Men Get Married, the Dormitory 8 series, The 5 Brides series, àti The Hidden Fantasy. Ní ọdún 2020, ó bẹ̀rẹ̀ eré báyému tí ó pè ní Discovering Princess Shyngle.
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 "Who is Princess Shyngle? All you need to know about her". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-08-27. Retrieved 2020-06-10.
- ↑ Gatwiri, Juster (2019-12-10). "All you ever wanted to know about Princess Shyngle". Yen.com.gh - Ghana news. (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-06-10.