Jump to content

Gánà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Orílẹ̀-èdè Olómìnira ilẹ̀ Gánà
Republic of Ghana

Flag of Gánà
Àsìá
Àmì ọ̀pá àṣẹ ilẹ̀ Gánà
Àmì ọ̀pá àṣẹ
Motto: "Freedom and Justice"
Location of Gánà
Olùìlú
àti ìlú tótóbijùlọ
Accra
5°33′N 0°12′W / 5.550°N 0.200°W / 5.550; -0.200
Àwọn èdè ìṣẹ́ọbaEnglish[2][3]
Lílò national languagesBritish English (official Language)
Àwọn ẹ̀yà ènìyàn
(2010[4][5])
Orúkọ aráàlúGhanaian
Ìjọba
• President
Nana Akufo-Addo
Mahamudu Bawumia
AṣòfinParliament
Independence from the United Kingdom
• Dominion
6 March 1957
• Republic
1 July 1960
28 April 1992
Ìtóbi
• Total
239,567 km2 (92,497 sq mi) (80th)
• Omi (%)
4.61 (11,000 km; 4,247 mi2)
Alábùgbé
• 2016 estimate
28,308,301[6] (45th)
• 2010 census
24,200,000[7]
• Ìdìmọ́ra
101.5/km2 (262.9/sq mi) (103rd)
GDP (PPP)2019 estimate
• Total
$211.127 billion[8]
• Per capita
$6,998[8]
GDP (nominal)2018 estimate
• Total
$68 billion[8]
• Per capita
$2,262[8]
Gini (2012)42.4[9]
medium
HDI (2017) 0.592[10]
medium · 140th
OwónínáGhanaian cedi (GHS)
Ibi àkókòUTC+0 (GMT)
Ojúọ̀nà ọkọ́right
Àmì tẹlifóònù+233
ISO 3166 codeGH
Internet TLD.gh

Gánà IPA: [gá.nà], jẹ́ orílẹ̀-èdè ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Afíríkà. Ní ìfọwọ́sí ''Republic of Ghana", jẹ́ orílẹ̀-èdè kan pẹ̀lú Gulf of Guinea àti Òkun Àtìláńtíìkì, ní orílẹ̀-èdè Ìwọ̀-oòrun Afíríkà. Gbígbà ibi-ilẹ̀ kan ti 238,535 km2 (92,099 sq mi), Gánà ń ko Ivory Coast ní ìwọ̀-oòrun, Burkina Faso ní àríwá, Tógò ní ìlà-oòrun, àti Gulf of Guinea àti Òkun Àtìláńtíìkì ní gúúsù. Ìlú Gánà túmọ̀ sí "Ọba Ajagun" ní èdè Soninke.[11]

Ìpínlẹ̀ àkọ́kọ́ tí ó wà títí ní agbègbè Gánà lónìí láti ọjọ́ kẹsàn-án ọdún 11 jẹ́, Ìpínlẹ̀ Bọ́nò ti ọ̀dúnrún náà.[12] Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìjọba àti àwọn ìjọba tó fara hàn ní àwọn ọ̀rúndún, èyí tó lágbára jù lọ ni ìjọba Dagbon [13] ati ìjọba Àṣáńtì.[14] Láti ọdún karùn-úndínlógún, ìjọba Ìlú Potogí, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè alágbára Yúróòpù mìíràn lẹ́yìn, díje agbègbè nítorí ìṣòwò, títí tí Ìjọba Gẹ̀ẹ́sì fi ìdí múlẹ̀ ìṣàkóso etíkun ní òpin ọdún 19k. Lẹ́yìn ọgọ́rùn-ún ọdún atakò ti àwọn ọmọ abínibí, ohun tí ó jẹ́ ààlà Gánà ní báyìí tẹ̀ lé ààlà tí èyí tí ó jẹ́ agbègbè ìjọba amúnisìn Gẹ̀ẹ́sì mẹ́rin ọ̀tọ̀tọ̀: Gold Coast, Àṣáńtì, Àwọn Agbègbè Àríwá àti Ilẹ̀ Tógò Gẹ̀ẹ́sì. Àwọn wọ̀nyí ni ìṣọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ìjọba olómìnira láàárín Ìjọba àpapọ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní oṣù kẹta, ọjọ́ kẹfà, ọdún 1957.[15][16][17]

Olùgbé Gánà tó tó mílíọ̀nù 30[18] ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀yà, èdè àti ẹ̀sìn àwọn ẹgbẹ́. Gẹ́gẹ́ bí ìkànìyàn ti 2010, 71.2% orílẹ̀-èdè jẹ́ onígbàgbọ́, 17.6% jẹ́ Mùsùlùmí, àti 5.2% jẹ́ onísìn ìbílẹ̀ tàbí kò sí ẹ̀sìn. [19] Onírúurú ilẹ̀ àti ìmọ̀-jìnlẹ̀ ti àwọn sàkánì láti ọ̀dàn etíkun sí igbó kìjikìji olóoru.

Orílẹ̀-èdè Gánà jẹ́ ìjọba tiwantiwa t’orílẹ̀-ede kan tó jẹ́ olùdarí nípasẹ̀ adarí kan tó jẹ́ orí orílẹ̀-èdè àti olórí ìjọba.[20] Ìdàgbàsókè ètò-ọrọ̀ ti ń mú Gánà dàgbà, ètò òṣèlú tiwantiwa sì ti jẹ́ kí Gánà jẹ́ orílẹ̀-èdè alágbára ní agbègbè òun ní Ìwọ̀-oòrùn Afíríkà.[21] Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ti Non-Aligned Movement, Ìṣọ̀kan Afíríkà (AU), Àgbàjọ Tòkòwò àwọn Orílẹ̀-èdè Ìwọ-oòrùn Afíríkà (ECOWAS), Ẹgbẹ́ 24 (G24) àti Àgbáyé ti Àwọn Orílẹ̀-èdè.[22]

Ìtàn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ère alámọ̀ Akan ti ọ̀dúnrún 16k, Metropolitan Museum of Art, Gánà
Máàpù ọdún 1850 tó fi ọmọ Akan Ìjọba Àṣáńtì nínú ìhà Gínì àti ẹkùn àyíká ní ìwọ̀-oòrùn Afíríkà hàn
Ọnà onídẹ Àṣáńtì ti ọ̀rúndún 18k tí wọ́n pè ní kuduo. Eruku wúrà àti ègé wúrà ni wọ́n fi pamọ́ nínú kuduo, àti ohun ìní míì náà. Gẹ́gẹ́ bí kóló fún kra ( ipá ìwàláàyè) ẹni tó ní i, kuduo ṣe kókó nínú ayẹyẹ fún bíbọ̀ onítọ̀hún.

A mọ Gánà gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ìjọba ńlá ní Bilad el-Sudan nípasẹ̀ ọ̀rúndún kẹsàn-án.[23]

Orílẹ̀-èdè Gánà ni ó wà láàárín ogoro àti Ọjọ-iwari nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìjọba Akan tó borí púpọ̀ jù lọ ní àwọn agbègbè Gúúsù ati Àárín gbùngbùn. Èyí pẹ̀lú Ottoman Àṣáńtì, Akwamu, Bonoman, Denkyira, ati ijọba Mankessim.[24]

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé agbègbè ti Gánà òde òní ni Ìwọ̀-oòrun Afíríkà ti ní ìrírí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àgbéká olùgbé, àwọn Akan ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní ọ̀rúndún karùn-ún.[25][26] Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún 11k, àwọn Akan ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nílùú Akan tí wọ́n pè ní Bonoman, èyí tí a dárúkọ Ekun Brong-Ahafo.[25][27]

Láti ọ̀rúndún kẹẹ̀dógún, àwọn ọmọ Akan ti inú ohun tí a gbàgbọ́ pé ó ti jẹ́ agbègbè Bonoman, láti ṣẹ̀dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú Akan ti Gánà, ní àkọ́kọ́ dá lórí òwò wúrà.[28] Àwọn ìpínlẹ̀ wọ̀nyí pẹ̀lú Bonoman (Ẹkùn Brong-Ahafo), Àṣáńtì (Ẹkùn Àṣáńtì), Denkyira (Ẹkùn Ìwọ̀-oòrùn Àríwá), ìjọba Mankessim (Ẹkùn Àárín gbùngbùn),àati Akwamu (agbègbè Ìlà-oòrun). Ní ọdún 19k, agbègbè ti ìhà gúúsù ti Gánà ni ó wà nínú ìjọba Àṣáńtì, ọ̀kan nínú àwọn ìpínlẹ̀ tó lágbára jù lọ ní ìhà aṣálẹ̀ Afíríkà ṣáájú ìbẹ̀rẹ̀ ètò amúnisìn.[25]

Ìjọba Àṣáńtì ṣiṣẹ́ ní ìṣáájú lọ́nà tí kò súnmọ́ tímọ́tímọ́, àti níkẹ̀yìn bí ìjọba àjùmọ̀ṣe pẹ̀lú ìlọsíwájú, iṣẹ́-ṣíṣe ayọ́gínní tó ga jù lọ tó dá ní olú-ìlú Kumasi.[25] Ṣáájú ìbáṣepọ̀ Akan pẹ̀lú àwọn òyìnbó, àwọn èèyàn Akan ti ṣẹ̀dá ètò-ọrọ̀ tó ní ìlọsíwájú tó dá lé lórí pàtàkì wúrà àwọn ọjà oníwúrà tí wọ́n tà sáwọn ìlú Afíríkà.[25][29]

Àwọn ìjọba àkọ́kọ́ tí a mọ̀ láti fara hàn nílùú Gánà ti òde òní ni àwọn ìlú Mole-Dagbani. Mole-Dagomba gẹṣin wá láti Burkina Faso ti òde òní lábẹ́ adarí Naa Gbewaa nìkan.[30] Pẹ̀lú àwọn ohun ìjà tó já fáfá àti tó dá lórí aláṣẹ àárín gbùngbùn kan, wọ́n tètè gbógun tì wọ́n sì tẹ̀ dó sí ilẹ̀ èèyàn agbègbè Tendamba (àwọn àlùfáà ọlọ́run ilẹ̀) wọ́n ṣàkóso wọn, wọ́n sì fi ìdí wọn múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ lórí àwọn abínibí, wọ́n fi Gambaga jọba.[31] Ikú Naa Gbewaa fa ìjà abẹ́lé láàárín àwọn ọmọ rẹ̀, díẹ̀ nínú àwọn tó kúrò láti tẹ̀ dó àwọn ìjọba ọ̀tọ̀tọ̀ pẹ̀lú Dagbon, Mamprugu, Mossi, Nanumba àti Wala.


Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 1. "Emefa.myserver.org". Archived from the original on 26 April 2012. Retrieved 21 December 2010. 
 2. "Language and Religion". Ghana Embassy. Archived from the original on 1 March 2017. Retrieved 8 January 2017. English is the official language of Ghana and is universally used in schools in addition to nine other local languages. The most widely spoken local languages are, Ga, Dagomba, Akan and Ewe. 
 3. "Ghana – 2010 Population and Housing Census" (PDF). Government of Ghana. 2010. Archived from the original (PDF) on 25 September 2013. Retrieved 1 June 2013. 
 4. "Ghana – 2010 Population and Housing Census" (PDF). Government of Ghana. 2010. Archived from the original (PDF) on 25 September 2013. Retrieved 1 June 2013. 
 5. "People > Ethnic groups: Countries Compared". NationMaster. Archived from the original on 14 July 2014. Retrieved 22 July 2014. 
 6. "2010 Population Projection by Sex, 2010–2016". Ghana Statistical Service. Archived from the original on 24 April 2018. Retrieved 2 May 2018. 
 7. Antoinette I. Mintah (2010). 2010 Provisional Census Results Out. 4 February 2011. Population Division, Ghana Government. Archived from the original on 15 June 2011. https://web.archive.org/web/20110615141322/http://www.ghana.gov.gh/index.php?option=com_content&view=article&id=4712%3A2010-provisional-census-results-out&catid=88%3Adaily-news-summary&Itemid=236. Retrieved 7 February 2011. 
 8. 8.0 8.1 8.2 8.3 "Report for Selected Countries and Subjects". www.imf.org. Retrieved 25 May 2019. 
 9. "GINI index (World Bank estimate)". data.worldbank.org. World Bank. Archived from the original on 25 January 2019. Retrieved 24 January 2019. 
 10. "2018 Human Development Report". United Nations Development Programme. 2018. Archived from the original on 14 September 2018. Retrieved 14 September 2018. 
 11. Jackson, John G. (2001) Introduction to African Civilizations, Citadel Press, p. 201, ISBN 0-8065-2189-9.
 12. Meyerowitz, Eva L. R. (1975) (in en). The Early History of the Akan States of Ghana. Red Candle Press. https://books.google.com/books?id=F3lyAAAAMAAJ. 
 13. Danver, Steven L (10 March 2015). Native Peoples of the World: An Encyclopedia of Groups, Cultures and Contemporary Issues. Routledge. pp. 25. ISBN 978-1-317-46400-6. https://books.google.com/books?id=vf4TBwAAQBAJ&pg=PA25&dq=Kingdom+of+Dagbon#q=Kingdom%20of%20Dagbon. 
 14. "Asante Kingdom". Afrika-Studiecentrum, Leiden. Archived from the original on 12 July 2014. Retrieved October 8, 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
 15. Àdàkọ:Cite video
 16. "First For Sub-Saharan Africa". BBC. Archived from the original on 1 November 2011. Retrieved October 8, 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
 17. "Exploring Africa – Decolonization". exploringafrica.matrix.msu.edu. Archived from the original on 2 June 2013. Retrieved October 8, 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
 18. "Ghana Population (2019) – Worldometers". www.worldometers.info (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 17 September 2018. Retrieved October 8, 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
 19. "2010 Population & Housing Census: National Analytical Report" (PDF). Ghana Statistical Service. 2013. p. 63. Archived from the original (PDF) on 12 July 2018. Retrieved October 8, 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
 20. CIA World FactBook. "Ghana". CIA World FactBook. CIA World FactBook. Archived from the original on 15 November 2013. Retrieved October 8. 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help); Check date values in: |access-date= (help)
 21. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named South America and West Africa
 22. "Ghana-US relations". United States Department of State. 13 February 2013. Archived from the original on 5 April 2013. Retrieved October 8, 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
 23. Levtzion, Nehemia (1973). Ancient Ghana and Mali. New York: Methuen & Co Ltd. p. 3. ISBN 978-0-8419-0431-6. 
 24. Title: Africa a Voyage of Discovery with Basil Davidson, Language: English Type: Documentary Year: 1984 Length: 114 min.
 25. 25.0 25.1 25.2 25.3 25.4 "Pre-Colonial Period". Ghanaweb.com. Archived from the original on 23 November 2010. Retrieved October 8, 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
 26. "Pre-European Mining at Ashanti, Ghana" (PDF) (PDF). Pdmhs.com. October 1996. Archived from the original (PDF) on October 8, 2020. Retrieved October 8, 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
 27. Tvedten, Ige; Hersoug, Bjørn (1992). Fishing for Development: Small Scale Fisheries in Africa. Nordic Africa Institute. pp. 60–. ISBN 978-91-7106-327-4. https://books.google.com/books?id=Itt1hIbsbQsC&pg=PA60. Retrieved October 8, 2020. 
 28. The Techiman-Bono of Ghana: an ethnography of an Akan society Kendall/Hunt Pub. Co., 1975
 29. "A Short History of Ashanti Gold Weights". Rubens.anu.edu.au. Archived from the original on 2 September 2013. Retrieved October 8, 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
 30. Jessica W (15 November 2011). "Invasion of the Peoples of the North". GhanaNation. Archived from the original on 8 July 2014. Retrieved October 8, 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
 31. Curtis M. (19 November 2011). "Ghana Articles: Dagomba". GhanaNation.com. Archived from the original on 19 October 2014. Retrieved October 8, 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)