Quincy Olasumbo Ayodele

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Quincy Sumbo Ayodele)
Jump to navigation Jump to search
Quincy Sumbo Ayodele
Ọjọ́ìbí Abeokuta, Ìpínlẹ̀ Ògùn,
Ibùgbé Ìlú Èkó, Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìgíríà
Orílẹ̀-èdè Ọmọ Nàìgíríà
Iṣẹ́ Onímọ̀ egbògi ìbílẹ̀ àti oníṣòwò
Known for Egbògi ìbílẹ̀
Title Olùdásílẹ̀
Children Mẹ́ta

Quincy Sumbo Ayodele ẹnití ìnagijẹ rẹ ń jẹ́  Quincy jẹ́ ọmọ Nàìjíríà oníṣẹ́ egbógi ìbílẹ̀, oníṣòwò,onímọ̀ egbògi amúni-tẹ́ẹ́rẹ́ áti olùdarì Quincy Herbal,olórí nínú àwọn ilé-iṣẹ́ tí n ta egbógi ìbílẹ̀ ni Nàìjíríà.[1] Ó jẹ́ olùdámọ̀ràn fún àjọ World Health Organization lórí egbógi ìbílẹ̀ àti ọmọ ẹgbẹ́ olùdámòràn fún àjọ yí kan na lórí ìdàgbàsókè áti kíkọ́ nípa egbógi ìbílẹ̀ ni ilẹ́ aláwọ̀ dúdú. Ó jẹ́ alágbàwị fún ìbásepọ̀ egbógi ìbílẹ̀ àti ètò- ìlera.  Quincy jẹ́ olùdásílẹ̀  Herbal Slimmers and Weight Loss Association of Nigeria áti asáájú akọ̀wẹ́ gboogbò fún Association of Traditional Medicine ni Naijiria.Ó jẹ̣́ olùdásílè  ilé-iṣẹ́ tí kí ń ṣe fún èrè, Self-Employed Women Association of Nigeria (SEWAN) tí n mójútó àwọn oníṣòwò lóbìnrin. Ṣaájú ìgbákalẹ̀ Quincy Herbal Slimmers, ó jẹ́ akọ̀wé ní ìfowópamó Societe Generale lẹ́hìn ná ní o di olùrànlówó pàtàkì fún alákóso àti olùdarí ilé- ìfowópamó na.[2]

Ìbẹ̀rẹ̀ Ayé àti Iṣẹ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Á bí ní ìlú Abékùta , olúìlú Ipinle Ìpínlẹ̀ Ògùn,Naijiria śinú ẹbí olóògbé olóyè Amos Oluwole Sodimu.[3] lẹ́hìn ìgbàtí àwọn òbí rẹ̀ lọsí ìdálẹ̀ (United Kingdom),ó lo ìgbà èwe rẹ̀ lọ́dọ̀ ìyá-àgbà, Mabel Osunmi Sodimu ní abúlé Ọlọ́rùnṣógo, ní ibi tí o tí kọ́ nípa egbògi ìbílẹ̀.[2] Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀kọ́ bẹ̀rẹ̀ ní African Church Primary School ní Abúlé Yambì áti ilé-ẹ̀kọ́ gị́ga Comprehensive High School, Ayétòrò ní ìpínlẹ̀  Ògùn. Lẹ́yìn èyí o lọ sí  Ogun State Polytechnic fún diploma ṣùgbọ́n kò ṣetán ní ilé-ẹ̀kọ́ yìí kí ó tọ́ lọ́ sí ìlú òkèrè ni Pitman’s Central College , London, ní b́i tí́ o gba Ìjẹ́rísí Higher Diploma nínú Secretarial Administration. Ó padà sí Nàìjíríà, ó sì darapọ̀ mọ́ ilé-ìfowópamọ́ Societe Generale Bank Nigeria Limited bí akọ̀wé, Lẹ́yìn èyí ní ó dí olùrànlọ́wọ́ pàtàkì si alákóso àti olùdarí  ilé-ìfowópamó ná.[4]

Quincy fí ipóyísílẹ̀ lẹ́hìn ọdún kejìlá ní ilé-ìfowópamọ́ yí láti dá iṣẹ́ tirẹ́ sílẹ̀.Sáájú ìdásílẹ̀ Quincy Herbals, ó gba ìwé-ẹ̀rí diploma nínú Natural medicine láti the Nigerian College of Natural Medicine, a subsidiary of Federal Ministry of Science and Technology, Victoria Island, Lagos.Ó kọ́ ńipa Naturopathy ní Ìlú United States ó sí darapọ̀ mọ́ àwọn àpéjọ ọ̀mọ̀we lórí egbògi lórisíri ní ìlú China.[4]

Ó dá Quincy Herbals sílè pẹ̀lú ẹgbẹ̀dọ́gbọ̀n naira. Á pá kan nínú ìnáwó yí ni ó kójọ níbi tí́ ó tí ń ta puff-puff.[5] Lóni, Quincy Herbals tí gbà ọpọ̀lọpọ ẹ̀bùn nítorì ipa ribiri tí àwọn ojà rẹ́ ńse.[6] Die ninu awari rẹ́ lórí  herbal slimming ni slimming ring, slimming aroma and slimming water, slimming "gari" , natural skincare products gbogbo èyí ní ó ṣe apèjúwe rẹ́ ní  "Egbògi Ìbílè pánbélé" tí wọn fi ímọ́-íjínlẹ́ gbé kalẹ̀.[7]

Quincy jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ olùdámòràn fún aj̣o World Health Organizationis lórí ìdàgbàsókè áti kíkọ́ nípa egbógi ìbílẹ̀ ni ilẹ́ aláwọ̀ dúdú.[1] Ó jẹ́ alágbàwí fún ìbásepọ̀ egbógi ìbílẹ̀ pẹ̀lú ètò-ìlera.O j̣e olùdásílẹ̀ Herbal Slimmers and Weight Loss Association of Nigeria áti asáájú akọ̀wẹ́ gboogbò fún Association of Traditional Medicine ni Naijiria  (NANTMP)[8]Ó jẹ́ olùdásílè ilé-iṣẹ́ tí kí ń ṣe fún èrè, Self-Employed Women Association of Nigeria  (SEWAN) tí n mójútó àwọn obìrin òtàjà..[1][6]

Ítókasí Gbangba[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìgbésí Ayé Ara-Ẹni[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Quincy ni iyawo Engr. John Oladipo Ayọ̀délé.Ìgbéyàwó yí ní ìbùkún ọmọ mẹ́ta: Tóbi Ayọ̀délé Keeney, ẹnítí ó ka ẹ̀kọ́ gboyè láti ilé-ìwé University of Maryland, Baltimore, Marita Tola Abdul , John Temi Ayodele àti ọṃọ-ọmọ.

Ìtókasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]