Jump to content

Rachael Okonkwo

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Rachael Okonkwo
Rachael Okonkwo ní ọdún 2017
Ọjọ́ìbíNnenna Rachael Okonkwo
26 Oṣù Kàrún 1987 (1987-05-26) (ọmọ ọdún 37)
Ukpata
Orílẹ̀-èdèNaijiria
Orúkọ mírànNkoli
Iṣẹ́Oṣere, onijo
Ìgbà iṣẹ́2008–iwoyi
Gbajúmọ̀ fúnNkoli Nwa Nsukka
Websitenkolinwansukka.com

Nnenna Rachael Okonkwo (tí a bí ní Ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n, Oṣù Kaàrún Ọdún 1987) tí a mọ̀ sí Nkoli Nwa Nsukka jẹ́ òṣèré fíìmù ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà . Ó gbajúmọ̀ jùlọ fún fíìmù Nkoli Nwa Nsukka.[1]

Ìgbé ayé àti iṣẹ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Rachael Okonkwo wá láti Ukpata ní agbègbè Uzo Uwani ti Ìpínlẹ̀ Enúgu. Ó bẹ̀rẹ̀ eré ṣíṣe ní àkókò ìgbà tí ó wà lọ́mọdé, ṣùgbọ́n nítorí àìní àwọn ipa fíìmù ó yípadà sí iṣẹ́ ijó. Ó darapọ̀ mọ́ Nollywood ní ọdún 2007 lẹ́ni tó n ṣe àwọn ipa kékéèké. Ní ọdún 2008, ó ṣe ipa amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ fún Ini Edo àti Van Vicker nínu eré Royal War 2. Ní ọdún 2010 bákan náà, ó pẹ̀lu Patience Ozokwor àti John Okafor jọ ṣe apá kínní àti apá kejì eré Open and Close. Ipa àkọ́kọ́ rẹ̀ tó ṣe gbòógì wáyé ní ọdún 2014, níbi tí ó ti kó ipa asíwájú nínu eré Nkoli Nwa Nsukka gẹ́gẹ́ bi Nkoli.[2][3] Ìya rẹ kú ní ọdún 2020.[4]

Àwọn iṣẹ́ ìfẹ́ràn ọmọnìyàn rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ayẹyẹ ọjọ́ àjí'ǹde fún àwọn ọmọdé

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Rachael Okonkwo maá n ṣe agbátẹrù ayẹyẹ lọ́dọọdún, pẹ̀lú èróngbà láti pèsè àwọn ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ fún àwọn ọmọdé àti láti dá àwọn ènìyàn lára yá. Ó sọ pé ètò náà maá n jẹ́ kí òun ní ìbáraeniṣepò pẹ̀lú àwọn tí wọ́n fẹ́ràn òun. Ní ọdún 2015, Rachael ṣe agbátẹrù ẹ̀dà àkọ́kọ́ ti ayẹyẹ ọjọ́ àjí'ǹde fún àwọn ọmọdé pẹ̀lú èróngbà láti pèsè àwọn ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ fún àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ ní àkókò ayẹyẹ ọjọ́ àjí'ǹde ní Enugu.[5] Ní ọdún 2016 ẹ̀dà ẹ̀kejì tí ò wáyé ní Onitsha ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èrò ju ti àtẹ̀yìnwá lọ pẹ̀lú wíwá àwọn òṣèré akẹgbẹ́ rẹ̀ bi Ken Erics àti àwọn míràn.[6] Ẹ̀dà ti 2017, èyítí ó wáyé ní ìlú bíbí rẹ̀,Nsukka, ní àkójọpọ̀ àwọn ènìyàn tó lé ní 5000. Lára wọn ni àwọn gbajúgbajà bi Angela Okorie, Nonso Diobi, Slowdog, Ken Erics, Nani Boi, Eve Esin àti àwọn míràn. Ó tún rí àtìlẹyìn àwọn ilé-ìtajà ńlá, èyí tó mú kí ẹ̀dà ti ọdún náà tóbi ju àwọn tó ti ṣááju rẹ̀ lọ.[7]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]