Jump to content

Rizi Timane

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Rizi Timane

Rizi Xavier Timane ni ó jẹ́ olórin, Mínísítà,ònkọ̀wé, ẹni tí ó yí ara rẹ̀ padà sí ọkùnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà[1][2][3]

Ibẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Timane ní Ìpínlẹ̀ Èkó ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́jọ, orísiríṣi ìdàamú ni ó bá padé ní ọwọ́ awọn òbí àti olùṣọ́ agùtàn sọ́ọ̀ṣì wọn nígbà tí wọ́n ṣàkíyèsí wípé nkan ọkùnrin ati ti obìnrin ni ó wà lára òun nìkan. Lẹ́yìn èyí, wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ tí ó tó ogún fun láti lè yi padà kúrò lóbìnrin sí ọkùnrin.[4]

Ètò ẹ̀kọ́ ati iṣẹ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó kẹ́kọ́ nípaBusiness managementLondon àti Los Angeles. [5] Ó tún kẹ́kọ́ gboyè kejì nípa social work láti University of Southern California níbi tí ó ti kẹ́kọ́ nípa ẹ̀sìn, ẹ̀tọ́ àwùjọ ati akitiyan ní ilé-ẹ̀kọ́ Claremont School of Theology. Ó ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí òsìṣẹ́ ìlera fún àwọn ọmọdé tí wọ́n jẹ́ Transgender ní. St. John's Well Child and Family Centre in Los Angeles.[6]

Ní ọdún 2013, ó ke ìwé kan tí ó pe ní "An unspoken Compromise" tí ó jẹ́ ìwé tí ó tà jùlọ ní orí Amazon lábẹ́ ẹ̀ka Lesbian and Gay.[7] Ní ọdún 2014,ó gbé àwo orin kan tí ó pe ní "Love is Stronger" ní ọdún 2014. Ó sì tún gbé owó kalẹ̀ láti fi ran àwọn ọmọdé tí wọ́n nílò iṣẹ́ abẹ tí òun náà ti ṣe rí .[8] Ó fẹ́ ìyàwó rẹ̀ Christina Ros, ọdún 2017. Wọ́n sì ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó wọn ẹlẹ́karùn un irú rẹ̀ lẹ́yìn ọdún mẹ́wá tí wọ́n ti wà papọ̀.[9]

Àwọn ìtọ́ka sí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Ihenacho, Chinma (2017-04-11). "Meet Nigerian-born transgender Dr. Rizi Xavier Timane who is married to a woman (photos)". Legit.ng - Nigeria news. (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2021-09-07. Retrieved 2021-09-07. 
  2. "Rizi Timane: Movies, TV, and Bio". www.amazon.com. Retrieved 2021-09-07. 
  3. "Meet Four Known Nigerian Transgenders (PHOTOS)". Within Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-11-05. Retrieved 2021-09-07. 
  4. "Nigerian-Born Transgender Who Is Married To A Woman Had 20 Surgical Procedure To Transition From Female To Male". GhGossip (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-04-13. Archived from the original on 2021-09-07. Retrieved 2021-09-07. 
  5. "Photos: Nigerian-born transgender who is married to a woman had 20 surgical procedure to transition from female to male". Linda Ikeji's Blog (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-04-12. Retrieved 2021-09-07. 
  6. Fitzpatrick, Kyle (2018-06-26). "Rizi Timane Is Helping the Transgender Community, 1 Surgery at a Time". POPSUGAR News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-09-07. 
  7. "Rizi Timane: My Journey as a Transgender Nigerian". NoStringsNG – Voice of LGBTQ+ Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2016-07-29. Retrieved 2021-09-07. 
  8. "Nigerian singer helps others with transgender surgery fund". NBC News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-09-07. 
  9. "Photos Of Nigerian Transgender Man Dr. Rizi Xavier Timane & Wife". Gistmania (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-04-11. Retrieved 2021-09-07. 

Àdàkọ:Portal bar Àdàkọ:Authority control