Rotimi Williams

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Rotimi Williams jẹ́ àgbẹ̀ àti oníròyìn tẹ́lẹ̀. Ó ní oko ìrẹsì Kereksuk ni Ipinle Nassarawa tí ó jẹ́ ilé-iṣẹ́ ìrẹsì ìṣowò kejì tí ó tóbi jùlọ ní orílẹ-èdè Nàìjíríà nípasẹ̀ títóbi ilẹ̀.

Oko rẹ̀, èyítí ó wà ńi ìpínlẹ̀ Nasarawa ní àríwá Naìjíríà, wà lọ́wọ́lọ́wọ́ ní àwọn saare 45,000 àti pé ó gba bíi òṣìṣẹ́ 600 ti wọ́n jẹ́ ọmọ abínibí ìlú Nasarawa.[1]

Ẹ̀kọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó lọ sí ilé-ìwé girama King's College, ní ìlú Èkó. Ó kọ́ ẹ̀kọ́ ètò-ọrọ̀ ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Aberdeen, ní oŕlẹ̀-èdè Scotland àti pé ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè Masters ní Ìṣòwò láti ilé-ẹ̀kọ́ kan náà. Ó tẹ̀ síwájú sí School of Oriental and African Studies (SOAS), ní ibi tí ó ti gba oyè ẹ̀kọ́ Masters nípa Ìṣúná àti Idàgbàsókè Ìjìnlẹ̀.[2]

Iṣẹ́-ṣíṣe[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi ayànyànná ní European Economics and Financial Center ní Ìlú London ní ọdún 2007. Ó tẹ̀síwájú láti jẹ́ aṣoojú Áfíríkà ní Ìwé ìròhìn Euromoney ní ọdún 2008. Ó tẹ̀síwáju láti ṣiṣẹ́ ní First City Monument Bank ní ọdún 2008 níbi tí ó ti sọ pé àwọn ìfiyèsí rẹ̀ fún èka iṣẹ́-ògbìn bẹ́ẹ̀rẹ̀ sí dàgbà nítorí ilé-ìfowópamọ́ kò ní gba àwọn eto ìmúlò àti kí ó wọlé sí ilé-iṣẹ́ ọ̀gbìn. Ó kúrò ní ọdún 2010 láti bẹ̀rẹ̀ oko ìresì hekitari 45,000 ti Kereksuk ní ọdún 2012.[3]

Awọn itọkasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Nsehe, Mfonobong. "Meet The 35 Year-Old Entrepreneur Who Owns Nigeria's 2nd Largest Rice Farm". Forbes (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-05-15. 
  2. "Mr. Rotimi Williams | Global Expo". www.globalexpo.co.bw. Archived from the original on 2019-04-29. Retrieved 2019-05-15. 
  3. Alhassan, Amina; Ekokuje-Emadu, Prisca (2015-08-22). "‘Nigeria depended on imported rice for too long’". Daily Trust (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-05-15. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]