Samuel Adesina Gbadebo

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Samuel Adesina Gbadebo, èyí tí a tún mọ̀ sí Gbadebo II jẹ́ ọba ní orílẹ̀-èdè Naijiria tí ó di oyè Aláké ti ìlú Ẹ̀gbá mú. Ṣáájú kí ó tó di Alake, Gbadebo ṣe àwọn ètò ní Ìwọ̀-Oòrùn Nàìjíríà láti polongo iṣẹ́ àgbẹ̀.[1]

Ìgbésí ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Gbadebo ní oṣù kẹsàn-án odun 1908 sí ìdílé Oba Gbadebo I àti Esther Omolara. Ó lọ ilé ìwé girama ní Abeokuta. Ó di ọ̀jọ̀gbọ́n láàrin Egba Native Authority, níbi tí ó ti ní àǹfààní láti ṣíṣe pẹ̀lú Alake Ladapo Ademola, eni tí ó ní fẹ́ sí isẹ́ rẹ̀. Lẹ́hìn náà, ó darapọ̀ mọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ti Ilẹ́-iṣẹ́ Railway Nigeria gẹ́gẹ́ bi akọ̀wé, ó tún ṣiṣẹ́ ní ojú-irin àgbègbè Ìlà-Oòrùn àti Ìwọ-oòrùn Nàìjíríà. Ní ọdun1936, ó padà sí Abeokuta, ó ń síse pẹ̀lú awon Aláṣẹ Egba(Egba native authority). Ó kó ẹ̀kọ́ nínú ìmò igbó(forestry) ní Ìbàdàn, ó si di olórí àwọn tí ń rí sí ọ̀rọ̀ igbó ní Egba. Láàrin ọdun 1954 sí 1955, ó kẹ́kọ̀ọ́ ní British Foresty Commission. Nígbàtí ó padà sí Nàìjíríà, ó ṣiṣẹ́ fún àgbègbè Ìwọ-Oòrùn Nàìjíríà ní ṣíṣe ìfihàn iṣẹ́-ọ̀gbìn.[1]

Ní ọdun 1963, wọ́n fi jẹ òye Alake ti ilẹ̀ Egba. Léyìn ìgbà tí ó dé ipò yí, ó dá ìgbìmò ìdámọ̀ràn kalẹ̀ ní agbègbè mẹ́rin Abeokuta: Ake, Gbagura, Oke-Ona àti Owu. Àwọn ìgbìmò náà a ma fi ìpinu wọn ránṣẹ́ sí ìgbìmọ̀ agbegbe Abeokuta.[1] Bákan náà ni ó gbé ìgbìmọ̀ ìsọ̀kan kan dide láti ṣàkóso àwọn ọ̀ràn ti Ìgbìmọ̀ Agbegbe.[1] Ó sowọ́pọ̀ pẹ̀lú egbé NNA Akintola nígbà tí wàhálà òsèlú ṣẹlẹ̀ ní ìwọ̀ oòrùn ní láàrin ọdun 1964 sí 1966, ó sì fẹ́ bẹ̀rẹ̀ fún àtìlẹ́yìn wọn fún ilẹ̀ Egba.[2]

Ọdun 1971 ló papòdà, Oba Lipede ni ó rọ́pò rẹ̀. Òun jẹ àbúrò ọ̀kan lára àwọn òbí Oba Gbadebo III.

Àwọn Ìtókasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 "The Alake is 56 Today". The Morning Post (Lagos): p. 8. 28 September 1964. 
  2. Olufemi., Vaughan (2006). Nigerian chiefs : traditional power in modern politics, 1890s-1990s (Softcover ed.). Rochester, NY: University of Rochester Press. pp. 116. ISBN 1-58046-249-9. OCLC 78626951.