Jump to content

Egba Gbagura

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ẹ̀gbá Gbágùrá
Ẹ̀gbá Gbágùrá is located in Nigeria
Ẹ̀gbá Gbágùrá
Ẹ̀gbá Gbágùrá
Location in Nigeria
Coordinates: 7°9′39″N 3°20′54″E / 7.16083°N 3.34833°E / 7.16083; 3.34833
Country Nigeria
StateOgun State

Egba Gbagura jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìpísísọ̀rí márùn-ún tí Ẹ̀gbá pín sí. Èka yòókù ni Ẹ̀gbá Aké, Oke-Ona, Òwu àti Ibara(ìtàn fi yé wa pé apá Yewa ni Ibara wà lohnìí, pé kì í ṣe Ẹ̀gbá, bí ó tilè jé pé ìlú Abéòkuta náà ló wà). Ó jẹ́ ìlú ìbílẹ̀ tó pààlà pẹ̀lú ìlú mìíràn, láti mú kí ìṣèjọba rẹ̀ gà si.

Agura ti Gbagura ni olórí ìbílẹ̀ ti apá kan ìlú Ẹ̀gbá. Lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀ ni a ti rí olórí ìletò méjìléláàádọ́rin, tí orúkọ oyè wọn sì jé Báálè. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọn agbára kan náà ni Agura àti Aláké ní, àmọ́ lẹ́yìn ìṣèjọba àwọn amúnisìn, Alake ni a lè sọ pé ó jé olórí fún gbogbo ẹ̀ka tí Ẹ̀gbá pín sí.

Ìlú abínibí ti àwọn Ẹ̀gbá tó wà nínú igbó Ẹ̀gbá, jẹ́ èyí tí àwọn ọmọ Yorùbá tó ṣí kúrò ní ìlú mìíràn wá sí ilẹ̀ wa. Ní ìbámu pẹ̀lú ìwé Ìtàn àwọn YorùbáSamuel Johnson kọ, àwọn olóyè Èso ikoyi dara pọ̀ mọ́ Aláké ti ìlú Ẹ̀gbá láti ṣe ìdásílẹ̀ ìletò tuntun. [1] Títí di àsìkò Ogun Abele Nigeria tí ìparún dé bá Orílé-Ẹ̀gbá, ó ṣì wà.

Àwọn Ẹ̀gbá fìgbà kan gbé ní ìlú Ọ̀yọ́, títí di ìgbà tí ọmọ Ẹ̀gbá kan, tó ń jẹ́ Lisabi gbìmọ̀ ọ̀tẹ̀ mọ́ Aláàfin Ìlú Ọ̀yọ́ nígbà náà. Èyí ló mú kí wọ́n máa pe Lisabi ní bàbá àwọn ọmọ Ẹ̀gbá.gba people originally live in the Oyo Empire until a Egba, Lisabi, organised a revolt against the Alaafin of the Oyo Empire. Nitorina lisabi ni won fi ka baba awon Egba.

Àwọn ènìyàn tó lààmìlaaka láti Ẹ̀gbá Gbagura

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Oloye MKO Abiola, oníṣòwò Naijiria tí ó jáwé olúborí nínú ìdìbò láti yan Ààrẹ Naijiria ní oṣù kẹfà ọdún 1993
  • Arábìnrin Efunroye Tinubu, alágbára obìnrin ṣíwájú àwọn amúnisìn wa ní ilẹ̀ Naijiria
  • Alhaji Sarafa Tunji Ishola, olóṣèlú ilẹ̀ Nàìjíríà

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Johnson 1921.