Aláké ti ìlú Ẹ̀gbá
Aláké ti ìlú Ẹ̀gbá ni orúkọ oyè ọba ti ìlú Ẹ̀gbá, èyí tó wà ní Abẹ́òkúta, ní Ìpínlẹ̀ Ògùn, ní apá Ìwọ̀-oòrùn ilè Nàìjíríà.[1] Ẹ̀gbá pín sí Ẹ̀gbá Aké, Òwu, Oke-Ona, àti Gbagura.[2]
Ìtàn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Sagbua Okukenu di Aláké ti ìlú Ègbá tó kọ́kọ́ jẹ, ó sì jọba láti ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹjọ, ọdún 1854 wọ ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kẹjọ ọdún 1862.[3] Sáájù ìfisípò rẹ̀ ní ọdún 1846, wọ́n fi Shomoye joyè Adelé fún ọdún kan, láàárín ọdún 1845 wọ ọdún 1846. Lẹ́yìn ìpapòdà Ọba Okukenu ní ọdún 1862, Shomoye padà sórí oyè gẹ́gẹ́ bíi Adelé, ó sì lo ọdún mẹ́rin lórí oyè, láàárín ọdún 1862 wọ 1866. Lẹ́yìn èyí, wọ́n fi Oba Ademola I jọba ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣụ̀ kọkànlá, ọdún 1869.[4][5] Ó joyè fún ọdún mẹ́jọ títí tó fi papòdà ní ọjọ́ ogbọ̀n oṣù kejìlá, ọdún 1877.[6] Ní ọjọ́ kìíní oṣù kìíní, ọdún 1878, wọ́n yan Ọba Oyekan láti joyè Aláké ti ìlú Ẹ̀gbá. Ó lo ọdún mẹ́ta lórí oyè kó tó papòdà ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kejìlá, ọdún 1881. Lẹ́yìn náà, wọ́n yan Oluwaji sórí oyè ní ọjọ́ kesàn-án oṣù kejì, ọdún 1885, tí ó sì lo ọdún mẹ́rin.[7]
Lẹ́yì ọdún méjì tí ipò-ọba ṣófo, wọ́n yan Ọba Oshokalu sórí oyè ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kesàn-án, ọdún 1891. Ó jọba fún ọdún méje, títí wọ ọjọ́ kọkànlá oṣụ̀ kẹfà, ọdún 1898 tó papòdà.[8] Ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹjọ, ọdún 1898, Ọba Gbadebo I di Aláké ti ìlú Ẹ̀gbá. Ó lo ọdún méjì lóri oyè, ó sì papòdà ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún, ọdún 1920.[9] Lẹ́yìn ìpapòdà Ọba Gbadebo ní ọdún 1920, Ọba Ladapo Ademola II di Ọba tuntun. [10] Ó jọba fún ọdún méjìlélógójì, àmọ́ ó lo ọdún méjì léyìn odi, láàárín ọdún 1948 wọ oṣù kejìlá ọdún 1950.[11] Lẹ́yìn ìpapòdà rẹ̀ ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kejìlá, ọdún 1962, ipò-ọba ṣófo fún ọdún kan. Ní ọjọ́ kejìlá oṣù kẹjọ, ọdún 1963, wọ́n yan Ọba Adesina Samuel Gbadebo II sórí oyè.[12] Lẹ́yìn ìpapòdà Adesina Samuel Gbadebo II ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹwàá, ọdún 1971, Samuel Oyebade Lipede gorí oyè[13] Ó jọba fún ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, títí tó fi papòdà ní oṣù kejì ọdún 2005, èyí ló sì mú kí Adedotun Aremu Gbadebo III gorí oyè.[14][15][16]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Jaide, Don (26 December 2009). "The Egbas, the Owus, and the Dahomeans – African History". Rasta Livewire/africaresource.com. Retrieved 1 July 2022.
- ↑ "Nigeriaworld Feature Article - Egba-Owu controversy: The distortion of history". Archived from the original on 2023-02-03. Retrieved 2023-02-03.
- ↑ Adewunmi Elegbede. "Kingdoms of Nigeria, The Nigerian Database of Rulers, Kings, Kingdoms, Political and Traditional Leaders". Archived from the original on 2015-12-24. Retrieved 2023-02-03.
- ↑ "pointblanknews.com".
- ↑ "USA/Africa Dialogue, No 353: The King is not dead!".
- ↑ "Egba Progressive Association, Inc. - Alakes Of Egbaland". Archived from the original on 2023-02-03. Retrieved 2023-02-03.
- ↑ ""Chieftaincy and the State in Abacha's Nigeria: Kingship, Political Rivalry and Competing Histories in Abeokuta during the 1990s" by Nolte, Insa - Africa, Vol. 72, Issue 3, Summer 2002". Archived from the original on 2016-03-04. Retrieved 2015-01-03. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Nigeriaworld Feature Article - Alake of Egbaland dies, Who's next?". Archived from the original on 2023-02-03. Retrieved 2023-02-03.
- ↑ "National Portrait Gallery - Person - Ladapo Samuel Ademola II, King of Abeokuta".
- ↑ "Reference at allafrica.com".
- ↑ Akinniyi Savage, Dr (25 May 2010). LOCAL GOVERNMENT IN WESTERN NIGERIA: ABEOKUTA, 1830-1952.. ISBN 9781469116938. https://books.google.com/books?id=fc-QAAAAQBAJ&q=Adesina+Gbadebo,+Alake+of+Egba&pg=PT66.
- ↑ "Nigerian Nostalgia Project".
- ↑ "Nigeriaworld Feature Article - Oba Lipede restored the glory of Egbaland". Archived from the original on 2023-02-03. Retrieved 2023-02-03.
- ↑ Odunoye, Oladipo; Akinpelu, Olalekan; Ope-Agbe, ʻwale (1997). Oba Oyebade Lipede. ISBN 9789780272265. https://books.google.com/books?id=nFwuAQAAIAAJ.
- ↑ "Alake restores Lawson as Iyalode of Egbaland". The Punch - Nigeria's Most Widely Read Newspaper. Archived from the original on 2015-01-03. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Our Reporter (July 2016). "Lisabi Festival: Markets close in Abeokuta".