Sharon Ikeazor

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Sharon Ikeazor
Sharon Ikeazor
Minister of State Environment
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
August 21, 2019
AsíwájúIbrahim Usman Jibril
Executive Secretary
Pension Transitional Arrangement Directorate
In office
September 26, 2016 – August 20, 2019
AsíwájúNellie Mayshak
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí
Sharon Olive Ikeazor

28 Oṣù Kẹjọ 1961 (1961-08-28) (ọmọ ọdún 62)
Alma materGodolphin School
Ahmadu Bello University
University of Benin
Nigerian Law School

Sharon Ikeazor (bíi ni ọjọ́ kejìdínlógbọ̀n, oṣù kẹjọ ọdún 1961) jẹ́ agbejọ́rọ̀ àti olóṣèlú ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Óun ni akọ̀wé tẹ́lẹ̀ fún Pension Transitional Arrangement Directorate. Ní oṣù kẹjọ ọdún 2019, ó di mínísítà lórí ọ̀rọ̀ àyíká ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[1][2][3]

Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Sharon bẹ̀rẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ ilé ìwé alákọ̀bẹrẹ̀ ní St Mary's Convenant School ní ìlú Èkó. Lẹ́hìnnà, ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Queen of The Rosary College ní ìlú Onitsha. Ó parí ẹ̀kọ́ gíga rẹ̀ ní Yunifásítì Ahmadu Bello ní ọdún 1981, ó sì gboyè nínú ìmò òfin láti Yunifásítì tí Benin ní ọdún 1984.[4][5]

Iṣẹ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ikeazor tí ṣé onímọ̀ràn òfin fún àwọn ilé ìfowópámọ́ Nigeria Merchant Bank, Nederlansce MiddenstandBank àti Midas Merchant Bank. Ó si ṣẹ́ pẹ̀lú Shell Petroleum gẹ́gẹ́ bí agbejọ́rọ̀ ilé iṣẹ́ náà ṣáájú ìṣètò ilé iṣẹ́ òfin tirẹ̀ ni ọdún 1994. Ní ọdún 1999, ó jẹ́ akọ̀wé òfin àti alákóso iṣẹ́ àkànṣe fún Fluor Daniel Nigeria Ltd. Ikeazor di igbá kejì fún ìdàgbàsókè isòwò àti àwọn ìbátan ìjọba fún ilé iṣẹ́ onímọ̀ràn tí United States, Good Works International (GWI) láti ọdún 2003 títí di ọdún 2008.[6] Ikeazor jẹ́ aṣojú òfin fún Aṣọ Energy Resources Ltd tí ó wà ní Àbújá fún ọdún méjì (2008-2010). Ní ọdún 2011, ó díje fún ipò olórí àwọn obìnrin ni ìpínlè Nàìjíríà lábẹ́ ẹgbẹ́ Congress for Progressive Change (CPC), ó sì wọlé[7]. Ní ọdún 2016, ó di sẹ́nátọ̀ fún ìpínlè Anambra lábẹ́ ẹgbẹ́ APC.[8] Ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹjọ, ọdún 2019, Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Muhammadu Buhari fi ṣe mínísítà lórí ọ̀rọ̀ àyíká ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[9]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Breaking: Akume, Lai, Fallen,Saraki, Keyamo make Buhari's Ministerial list". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-07-23. Retrieved 2019-08-07. 
  2. "Faces of new lawyers in incoming cabinet". The Nation Newspaper (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-08-05. Retrieved 2019-08-07. 
  3. Adanikin, Olugbenga (2019-08-21). "Cabinet List: Buhari remains petroleum minister, appoints Sylva junior minister". International Centre for Investigative Reporting (ICIR). Retrieved 2019-09-21.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. "SHARON IKEAZOR". Women in politics forum (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2019-08-07. Retrieved 2019-08-07. 
  5. Yesufu, Joy (2019-04-04). "Exclusively Woman : Inside Sharon Ikeazor’s PTAD". Leadership Newspaper (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-08-07. 
  6. "GoodWorks International - Powerbase". powerbase.info. Retrieved 2019-08-07. 
  7. Olaode, Funke (April 12, 2015). "Sharon Ikeazor: I have Faith in Buhari". Thisday Newspaper. https://www.pressreader.com/nigeria/thisday/20150412/page/58. 
  8. "Sharon Ikeazor Emerges APC Candidate For Anambra Senatorial Candidate". NewsWireNGR (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2016-01-23. Retrieved 2019-08-07. 
  9. "JUST IN: Full List: Buhari assigns portfolios to new Ministers". Oak TV Newstrack. 21 August 2019. Archived from the original on 26 August 2019. https://web.archive.org/web/20190826102219/https://oak.tv/newstrack/full-list-buhari-assigns-portfolios-ministers/. Retrieved 26 August 2019.