Sheik Muyideen Àjàní Bello

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Sheik Muyideen Àjàní Bello jé Àfáà nlá oní wáàsí lójú ònà Mùsùlùmí, àti omo bíbí ìlú Ìbàdàn, ó jé omo àádórin odún.

Ìgbé ayé rè[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Sheik Muyideen Àjàní Bello bèrè isé wáàsí ìta gbangba nígbà tí ó wà ní omo odún méwàá léyìn tí ó ti kó nípa ìmò Alùkùránì lábé bàbá rè tí ó jé Àfáà àgbà nílùú Àgberígbe tí ó jé ìletò kan nílùú Ìwó. Lásìkò tí ó wà ní omo odún mésàán ni ó lo gbé lófò àbúrò bàbá rè tí òun náà náà jé Àfáà oníwáàsí ìta gbangba tí ó sì tún nílé kéwú nílùú Ìbàdàn.[1]

Ètò èkó rè[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Léyìn tí Muyideen dé òdò àbúrò bàbá rè, ó bèrè ilé iwé alákòó-bèrè níbàdàn, tí o sì tún n fojú sékòó Àlùkùránì ní ìròlé tí ó bá dé láti ilé iwé rè. Léyìn èyí, ó lo sí ilé èkó girama àtivilé èkó àwon olùkó (N.C.E). Ó sebisé olùkóni ní ilé iwé Ansa-ru-deen College tí ó wà ní ìlú Sakíìpínlè Òyó. Ó tún se isé olùkó ní ìwé girama Abeokuta,níbi tí ó to kó èkó àti èkó Biology.[2]

Àwon ìtóka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Opeyemi, Oyebajo (2018-04-20). "THE FAITHFUL – The birth and life of sheikh Muyideen Ajani Bello Part 1". HappeningsTV. Retrieved 2018-11-07. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  2. "Sheikh Muyideen Ajani Bello". Encomium Magazine. 2017-12-16. Retrieved 2018-11-07.