Simi bedford

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Simi Bedford jẹ́ òǹkọ̀we láti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí ó tẹ̀dó sí ìlu Britain. Ìwe rẹ̀ akọ́kọ́ Yoruba Dancing Girl, jẹ́ ìtan ìgbésí-ayé-ara-ẹni nípa ọ̀dọ́mọbìrin Nàìjíría kan ti wọ́n rán lọ sí orílẹ̀-ède England láti lọ kọ́ ẹ̀kọ́ ni ilé-ẹ̀kọ́ àdáni, wọ́n ṣe àyẹ̀wo ìwé náà ní ibi ìtẹ̀wé tí ó sì di kókó ìsọníṣókí fún BBC Radio.[1] Ìwe rẹ̀ ẹ̀kejì, Not With silver, ni o ṣe àtẹ̀jáde rẹ̀ ni ọdún 2007.

Ìtàn Ìgbésí-ayé[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Bedford sí ìlú èkó, ní Nàìjíríá[2], ti àwọn òbi rẹ̀ wá láti Sierra Leone.[3] Àwọn bàbá-ńlá rẹ̀ àgbà jẹ́ abínibi Nàìjíríá, tí wọ́n kóyọ láti inú ọkọ̀ ẹlẹ́rú.[4] Bedford ṣe ìgbà èwe rẹ̀ ní ìlu èkó, kí ó tó kọjá lọ sí Britian[5] fun ẹ̀kọ rẹ̀, níbití ó tí lọ sí ilé-ị̀we aṣètò-fún akẹ́kọ̀ọ́ láti ọmọ ọdún mẹ́fà.[6]

Ó kọ́ nípa ìdájọ́ ni Durham University, lẹ́yìn èyítí ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi atọ́kùn ètò lóri ẹ̀rọ rédíò ati lóri ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán gẹ́gẹ́ bíi awámọ̀. Ó gbé ní ìlu London, níbiti ó ti lọ́kọ tí ó sì tọ́ awọ̀n ọmọ mẹ́ta dàgbà. Ṣùgbọ́n ìyapa ti wà láàrín òun àti ọkọ rẹ̀, Martin Bedford tí ó jẹ́ òṣèré, ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣì jọ ń dọ́rẹ̀ẹ́, tí wọ́n sì jọ ń gbé pọ̀ ní ilé kan náà ni ilu Devon.[7]

Ìwé kíkọ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìwe àkọ́kọ́ tí Bedford kọ ni Yoruba Dancing Girl tí ó fẹ́ farapẹ́ ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀, níbití ó ti sọ ìríri ọmọbìrin Nàìjíríà kan tí ó lọ kàwé ní ìlu Britain,[8] tí Francine Prose ti Washington ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bi "àgbékalẹ̀ dáradára... tí ó múnilọ́kàn, tí ó sì jẹ́ òtítọ́ pọ́ńbélé nípa ohun tí yóò gbani láti fi ìlú sílẹ̀ àti ìsúnrakì." [9]Ìsọníṣókí onípele-márùn-ún ti ìwe Yoruba Girl Dancing (lati ọwọ Magaret Busby, tí Adjoa Andoh kà, tí David Hunter sì ṣe àtẹ̀jáde rẹ̀) ni wọ́n gbé jáde lóri BBC redìò, pẹ̀lú àkọ́le Book at Bedtime ní ọdún 1991. [10] Inú àkójọpọ̀ ìwe Busby, New Daughters of Africa ti ọdún 2019 ni wọ́n ti gbé e jáde.[11][12]

Ìwé kejì tí Bedford, Not with Silver (2007), jẹ́ ìtàn àròsọ, tí ó dálélórí sẹ́ńtúrì kejìdíńlógún ní àríwá Áfíríkà, ìkónilẹ́rú àti ìdájọ́.[13] Nípa ìmọ òǹkọ̀wé nípa ìṣẹ̀ńwáyé, Not with Silver dáyàtọ̀ láàrín àwọn ìwé tí ó ń sọ nípa òwò ẹrú tí ó sì ń sọ nípa ìgbési ayé àwọn ènìyan Áfíríkà kí wọ́n tó kó wọn lẹ́rú[14] The SpectatorÀdàkọ:'s reviewer concluded: "This relentlessly honest book has no false or sentimental notes, absolutely no prettifying. A black warrior facing unexpected danger is taught to imagine the worst, 'look the leopard in the eye.' Simi Bedford does just that. A brave and uncomfortable labour of love."<ref>. Òǹwòran náà sọ ní àkótán pé "Ìwe olótìítọ yìí kò fàyè gba irọ́, kò sì pọ́n jẹ̀bẹ̀ lákìísà. Jagunjagun aláwọ̀ dúdú tí ó dojúkọ ìjàm̀bá, kí ó maa retí ohun tí ó burú, 'wo ẹkùn lójú.' Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni Simi Bedford ṣe. Èyí tí ó jẹ́ iṣẹ́ Ìgboyà àti àtinúwá.[15]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Hodapp, James, "The Proto-Afropolitan Bildungsroman: Yoruba Women, Resistance, and the Nation in Simi Bedford's Yoruba Girl Dancing", The Global South, Volume 10, Number 1, Spring 2016, pp. 130–149.
  2. Leese, Peter, Britain Since 1945: Aspects of Identity[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́], Palgrave Macmillan, 2006, p. 50.
  3. Simi Bedford interview on Woman's Hour, BBC Radio 4, 25 July 2007. YouTube.
  4. "Bedford's 'Complete' Slave Picture". BBC News. 3 September 2007. http://news.bbc.co.uk/2/hi/africa/6972124.stm. 
  5. Cooper, Brenda (2011). Stories Fly: A Collection of African Fiction Written in Europe and the USA. New Africa Books. pp. 60. ISBN 9780864866080. 
  6. "Simi Bedford", Black British Women Writers.
  7. Hodgkinson, Liz (20 July 2015). "Divorced? You Can Be Friends With Your Ex. I Should Know.". The Telegraph. https://www.telegraph.co.uk/goodlife/11705449/Friends-after-divorce-It-is-possible.-I-should-know.html. 
  8. Griswold, Wendy (2000). Bearing Witness: Readers, Writers, and the Novel in Nigeria. Princeton Studies in Cultural Sociology. pp. 26–27. ISBN 978-0691058290. https://books.google.com/books?id=kf7_x8yz430C&q=%22simi+bedford%22&pg=PP1. 
  9. Prose, Francine (27 September 1992), "England through young African eyes", Washington Post.
  10. "Listings", Radio Times, Issue 3539, 23 October 1991, p. 93.
  11. Busby, Margaret (9 March 2019), "From Ayòbámi Adébáyò to Zadie Smith: meet the New Daughters of Africa", The Guardian.
  12. New Daughters of Africa contributors, Myriad Editions.
  13. Dabydeen, David (30 August 2007). "Not With Silver, by Simi Bedford". The Independent. https://www.independent.co.uk/arts-entertainment/books/reviews/not-with-silver-by-simi-bedford-463597.html. 
  14. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named :02
  15. Durrant, Digby, "Pity the oppressed; fear the oppressed", The Spectator, 7 November 2007.