Solomon Babalọlá
Solomon Adébóyè Babalọlá ni wọ́n bí ní ọjọ́ Kẹtàdínlógún oṣù Ọ̀pẹ, ọdún 1926, ó kú ní ọjọ́ Kẹèdógún oṣù Kèjìlá, ọdún 2008 (December 17, 1926- December 15, 2008), ní ilú Ìpetumodù, ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ Olùkọ́, akéwì àti onímọ̀.[1]
Ìgbésí ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọ̀jọ̀gbọ́n Solomon Adébóyè Babalọlá jẹ̀ ọmọ ìdílé Babalọlá ti Ilé - Ajo. Bàbá rẹ̀ Joseph Olawuni Omowumi Babalola (Ajala) jẹ́ gbẹ́nà-gbẹ̀nà, ní sẹ́nútúrì ogún ó tún ilé àwọn èèyàn tí ìjì wó kọ́, wọ́n mọ́ rírí Ìfọmọnìyànṣe àti àánú rẹ̀ yìí, wọ́n sì fún ìdílé wọ́n ni orúkọ "Alatunse ti Ìpetumodù". Ẹlẹ́ṣìn ìgbàgbọ́ ni bàbá rẹ̀. Wọ́n ṣe ìrìbọmi fún sínú ìjọ Soosi Kírísítì tí Ṣọ́ọ̀sì àwọn Àjìhìnhere Christ Church of the Church Missionary - C. M. S). Wọ́n fi ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ tọ́ ní kékeré, ó lọ sí Iléẹ̀kọ́ Alákọ̀bẹ́ẹ̀rẹ̀ Kírísítì (Christ Primary School), Wásìimi, Ìpetumodù. Akọrin Ṣọ́ọ̀sì ni, tí ó sì má ń kọrin nínú balùwẹ̀ nígbà ayé rẹ̀. Babalọlá gba Kírísítì gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run àti Olùgbàlà rẹ̀ nígbà tí ó wà ní Kọ́lẹ́jì Igbóbì, tí Bisoopu Rt. Rev Gordon tí ìlú Èkó sì ṣe ìjẹ́rìsí.
Babalọlá lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Achimota College ní orílẹ̀ èdè Ghana. lẹ́yìn tí ó kẹ́kọ̀̀ọ́ gboyè tán ní ọdún 1946, ó ṣiṣẹ́ olùkọ́ ní Igbóbì College. Ní ọdún1948, ó gba ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ẹlẹ́kejì láti kọ́ ẹ̀kọ́ nílé ẹ̀kọ́ Queens' College, Cambridge, níbi tí ó tún ti gba oyè ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ẹlẹ́ẹ̀kejì ní ọdún 1952. Ó tuń padà sí Igbóbì College láti tẹ̀ síwájú lórí iṣẹ́ ìkọ́ni rẹ̀ tí ó sì rí àgbéga tí ó fi di olùkọ́ àgbà tí ó jẹ́ adúláwọ̀ ilé-ẹ̀kọ́ náà , pẹ̀lú bí ó ṣe jẹ́ wípé òun ni olùkọ́ tí ọjọ́ orí rẹ̀ kéré jùlọ nínú àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ náà. Wọ́n fun ni ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ Ọ̀mọ̀wé (doctoral scholarship) nínú lítíréṣọ̀ èdè Yorùbá. Ní ọdún 1962, wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ Institute of African Studies ti Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ University.[2] Ó tún jẹ ànfàní ètò ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ lọ sílé ẹ̀kọ́ University of London láti gba oyè ìmọ̀ Ọ̀mọ̀wé. Ní ọdún 1963 , ó di ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ èdè ilẹ̀ adúláwọ̀ (professor of African Languages) ní ilé ẹ̀kọ́ University of Lagos. Ní ọdún 1966, ó tẹ ìwé The Content and Form of Yoruba Ijala,tí ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé Oxford University Press gbé jáde. Iṣẹ́ náà sọ nipa àlọ́ onítàn Yorùbá,àwọn ewì lóríṣiríṣi àti àkójọpọ̀ àwọn ewì Ìjálá Ọdẹ (hunter's songs), tí wọ́n ṣògbufj78ọ̀ rẹ̀ sí èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ìwé náà gba àmì ẹ̀yẹ ti Amaury Talbot Prize fún iṣẹ́ tó peregedé jùlọ lọ́dún náà fún lítíréṣọ̀ àwọn ènìyàn apá Iwọ̀-Oòrùn ilẹ̀ Adúláwọ̀. Ìwé náà tún ṣílẹ̀kùn fún ìwádí nípa èdè ìlè Adúláwọ̀ ní gbogbo àbgáyé, lábẹ́ àkóso Babalọlá ní University of Lagos. Ẹ̀ka ẹ̀kọ́ tó èdè Adúláwọ̀ ati Asian ní wọ́n dá ní sílẹ̀ ní odun 1967 ni Yunifásítì Àpapọ̀ ti Ìlú Èkó , ní èyí tí Babalọlá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ mẹ́ta ẹ̀ká ẹ̀kọ́ náà, wọ́n gbajúmọ́ èdè Abínibí ilẹ̀ Nàìjíríà tó gbajúmọ̀ Nigerian languages: Yoruba, Igbo, Edo ati Hausa.[3] À
Àwọn iṣẹ́ àpilẹ̀kọ Babalọlá kó ipa ribiribi fún ìsọlọ́jọ àwọn Lítíréṣọ̀ alohùn. Babalọlá wọ káà ilẹ̀ lọ ní ọjọ́ Kẹèdógún oṣù Ọ̀pẹ, ọdún 2008
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "S. Adeboye Babalola". Encyclopedia Britannica. 1926-12-17. Retrieved 2018-05-22.
- ↑ "Merriam-Webster's Encyclopedia of Literature". Google Books. Retrieved 2018-05-22.
- ↑ "Brief History of the Department of African and Asian Studies [archived]". About Us - Faculties of ARTS »» Department AFRICAN & ASIAN STUDIES [archived]. University of Lagos. Archived from the original on 19 April 2018. Retrieved 18 April 2018.
- People from Osun State
- Nigerian academics
- Nigerian male poets
- Yoruba poets
- Alumni of the University of London
- Yoruba academics
- Yoruba-language writers
- Alumni of Achimota School
- Obafemi Awolowo University faculty
- University of Lagos faculty
- Alumni of Queens' College, Cambridge
- Yoruba-language poets
- Nigerian educators
- Yoruba educators
- Nigerian folklorists
- Nigerian schoolteachers
- 20th-century Nigerian poets
- 20th-century Nigerian educators
- Àwọn ọjọ́ìbí ní 1926
- Àwọn ọjọ́aláìsí ní 2008