Jump to content

Susan Basemera

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Susan Basemera
Orílẹ̀-èdèUgandan
Orúkọ mírànZani Lady C
Iṣẹ́Singer, actress
Ìgbà iṣẹ́1995-present

Susan Basemera jẹ́ akọrin àti òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Ùgándà.

Basemera bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ lọ́mọ ọdún mẹ́jọ ní ìgbà tí ó fi wà nínu ẹgbé akorin ti ilé-ìwé rẹ̀. Àwọn ará orílẹ̀-èdè rẹ̀ mọ̀ọ́ sí Zani Lady C. Ó di gbajúmọ̀ nígbà tí ó fi darapọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ akọrin kan tí wọ́n pè ní Waka Waka àti pẹ̀lú ṣíṣe orin tí ó pe àkọ́lé rẹ̀ ní "Yimilila awo" ní ọdún 1995.[1] Ní ọdún 2012, Basemera lọ sí Amẹ́ríkà láti tẹ̀síwájú nídi iṣẹ́ rẹ̀. [2] Bótilẹ̀jẹ́pé ó ti gbájúmọ́ ṣíṣẹ eré ìtàgé, ó tún gbé orin kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ "Goolo Goolo" jáde ní ọdún 2015.[3]

Ní ọdún 2016, Basemera kópa nínu eré oníṣókí kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Gubagudeko ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Mahershala Ali. Ní ọdún 2020, Basemera kópa nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Little America, eré tí ó dá lóri àwọn àtọ̀hún-rìnwá ilẹ̀ Amẹ́ríká. Ó rí ànfàní ipa náà lẹ́hìn tí ó kàn sí olùdarí eré náà tó sì ṣe dáada níbi àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe fún fíìmù náà.[2]

Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • 2012: Love Collision (voice)
  • 2016: Gubagudeko
  • 2016: Can You Keep a Secret
  • 2020: Little America

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Zani Bio". Music in Africa. Retrieved 14 October 2020. 
  2. 2.0 2.1 e Am Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; name "monitor" defined multiple times with different content
  3. "I am focusing on my acting career at the moment -- Singer Zani Lady C". https://www.sqoop.co.ug/201910/four-one-one/i-am-focusing-on-my-acting-career-at-the-moment-singer-zani-lady-c.html. Retrieved 14 October 2020. 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]