Teresa de Lauretis
Teresa de Lauretis - Wọ́n bí Teresa de Lauretis ní ìlú Bologna ni 1938. Ó jẹ́ òǹkọ̀wé ọmọ Ìtàló, ó sì jẹ́ Àgbà-ọ̀jẹ Ọ̀jọ̀gbọ́n ẹ̀kọ́ Ìtàn ìtaraẹnijí ní ilé-ẹ̀kọ́ Yunifásítì California, Santa Cruz. Àwọn iṣẹ́ tí ó jẹ ẹ́ lógún ni àwọn àtúpalẹ̀ iṣẹ́-ajẹmọ́kàn, àmì-lílò, tíọ́rì fíìmù, tíọ́rì liítíréṣọ̀, ìṣègbèfábo, Ìmọ̀ ìṣẹ̀dá - irin kan náà. Ó gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Ìtàló, èdè méjèèjì ni ó fi ń kọ iṣẹ́. Ní àfikún, wọ́n ti ṣe ògbufọ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀ sí èdè mẹ́rìndínlógún mìíràn.
Ó gba òye Ọ̀mọwé ni èdè àti liítíréṣọ̀ òde-òní láti Yunifásítì Bocconi ni Milan kí ó tó wá sí United States. Ó darapọ̀ mọ́ Ẹ̀kọ́ ìtàn àti ìtaraẹnijí. pẹ̀lú Hayden White, Donna Haraway, Fredic Jameson àti Angela Davis. Ó ti lọ ṣiṣẹ́ káàkiri àwọn yunifásítì lágbàáyé lára wọn ni Canada, Germany, Italy, Sweden, Spain, Austria, Argentina, Chile, France, Hungary, Croatia, Mexico àti Netherlands. San Francisco ló fi ṣe ibùgbé lọ́wọ́lọ́wọ́, ṣùgbọ́n ó má ń ṣeré lọ sí Italy àti Netherlands[1]