The Owo Museum
Ìrísí
Ilé ìṣẹ̀mbáyé Ìlú Ọ̀wọ̀ jẹ́ ilé ìṣẹ̀mbáyé ńlá kan tí ó wà ní ìlú ìlú Ọ̀wọ̀, ní Ìpínlẹ̀ Òndó ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Wọ́n da ilé ìṣẹ̀mbáyé náà sílẹ̀ ní ọdún 1968 láti lè kó àwọn ohun ìṣẹ̀mbáyé ayé àtijọ́ tí kò sírú rẹ̀ mọ́ síbẹ̀. Inú àgbàlá ààfin Ọlọ́wọ̀ ni Ilé ìṣẹ̀mbáyé yí wà tẹ́lẹ̀. Ilé ìṣẹ̀mbáyé náà ní àwọn ohun mèremère tí wọ́n jẹ́ ohun ayé àtijọ́ nínú.[1] Ọdún 9169 sí 1971 ni wọ́n kọ́kọ́ wa àwọn ohun ìṣẹ̀mbáyé kan jáde láti ọwọ́ Ekpo Eyo nínú ilẹ̀ ní Ìlú Ọ̀wọ̀ lábẹ́ àbójútó ẹ̀ka ìjọba tí ó ń rí sí ohun àlùmọ́nì ayé àtijọ́. Àwọn ohun tí wọ́n rí wà jáde nínú ilẹ̀ náà ni terracotta sculptures tí wọ́n ti ló tó sẹ́túrì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sẹ́yìn. Ìdíbni wípé, ìlú Ọ̀wọ̀ jẹ́ ìlú tí ó wà ní àárín gbùngbùn Ilé-ifẹ̀ àti Ilẹ̀ Ìbíní.[2]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Nigerian Embassy
- ↑ "Owo Museum of Antiques Ondo State :: Nigeria Information & Guide". www.nigeriagalleria.com. Retrieved 2023-07-12.