Theresa Traore Dahlberg

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Theresa Traore Dahlberg
Dahlberg in 2019
Ọjọ́ìbíOṣù Kọkànlá 1, 1983 (1983-11-01) (ọmọ ọdún 40)
Värnamo
Orílẹ̀-èdèSwedish
Iṣẹ́Film director, screenwriter
Ìgbà iṣẹ́2006-present

Theresa Traore Dahlberg (tí wọ́n bí ní 1 Oṣù Kọkànlá Ọdún 1983) jẹ́ olùdarí eré àti ònkọ̀tàn ọmọ orílẹ̀-èdè Swídìn àti Bùrkínà Fasọ̀

Isẹmi rẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Dahlberg jẹ́ ọmọ sí akọrin ilẹ̀ Bùrkínà Fasọ̀ kan tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Richard Seydou Traore. Ó dàgbà ní Bùrkínà Fasọ̀ àti ní ìlú Öland tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Swídìn.[1] Àwọn òbí rẹ̀ ṣiṣẹ́ fún Àjọ Àgbáyé fún ètò ìdàgbàsóké ní orílẹ̀-èdè Bùrkínà Fasọ̀. Lẹ́hìn tí Dahlberg parí ilé-ìwé girama rẹ̀, ó kó lọ sí ìlú New York ní Orílẹ̀-èdè Ìṣọ̀kan Amẹ́ríkà, níbi tí ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iṣẹ́ tó fi mọ́ èyí tí ó ṣe nínu ọgbà ìṣeré kan. Ní ọdún 2007, ó forúkọsílẹ̀ ní ilé-ìwé The New School tí ó wà ní ìlú New York.[2] Dahlberg gba oyè-ẹ̀kọ́ láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Stockholm Academy of Dramatic Arts, bẹ́ẹ̀ ló sí tún gba oyè gíga nínu ìmọ̀ Fine Arts láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Royal Academy of Arts.[3]

Dahlberg darí àkọ́kọ́ fíìmù oníṣókí rẹ̀ ní ọdún 2006. Ó tún ṣe àgbéjáde eré ọgbọ̀n-ìṣẹ́jú kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ On Hold ní ọdún 2009. Lẹ́hìn náà, Dahlberg ṣiṣẹ́ fún àwọn ètò tẹlifíṣọ̀nù ti Swídìn, ó sì darí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn eré.[4] Ní ọdún 2011, ó ṣe adarí eré ìrírí oníṣókí kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Taxi Sisters, èyí tí ó dá lóri àwọn obìnrin awakọ̀ kabúkabú ní orílẹ̀-èdè Sẹ́nẹ́gàl. Ní ọdún 2017, Dahlberg darí eré gígùn tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Ouaga Girls. Fíìmù náà dá lóri àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ilẹ̀ Bùrkínà Fasọ̀ tí wọ́n ti yàn láti máa ṣiṣẹ́ atọ́kọ̀ṣe.[5] Eré náà ṣàfihàn ìgbésí ayé wọn ní ìgbà tí wọ́n wà ní ilé-ìwé àti lẹ́hìn tí wọ́n jáde ilé-ìwé, ó sì ṣàlàyé àwọn ìdí tó mú kí wọ́n yàn láti máa ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ - àwọn kan nínu wọ́n ti pàdánù àwọn òbí wọn, bẹ́ẹ̀ làwọn míràn síì ti lọ ní oyún ẹlẹ́yà nígbà tí wọ́n n dàgbá bọ̀.[6] Ouaga Girls gba àmì-ẹ̀yẹ ti CREDIF níbi ayẹyẹ Carthage Film Days.[7] Dahlberg darí eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ The Ambassador's Wife ní ọdún 2018. Fíìmù náà gba àmì-ẹ̀yẹ Tempo Documentary Short Award, tí Dahlberg náà fúnrarẹ̀ síì gba àmì-ẹ̀yẹ ti Beckers Art Award ní ọdún 2019.[8]

Yàtọ̀ sí ṣíṣe iṣẹ́ fíìmù, Dahlberg tún maá n ṣiṣẹ́ agbẹ́gilére. Ó kópa pẹ̀lú ilé-àwòrán Tensta Konsthall Art Gallery tí ó wà ní ìlú Stockholm nínu àwọn iṣẹ́ àkànṣe kan tí wọ́n pè ní Solidarity Projects.[9]

Àṣàyàn àwọn eré tí ó ti darí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • 2006: Procastistation
  • 2009: On Hold
  • 2010: Två på resa (Two Travelling) (TV series, two seasons)
  • 2011: Taxi Sister
  • 2017: Ouaga Girls
  • 2018: The Ambassador´s Wife

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Zuiderveld, Maria (25 August 2017). "Normbrytande kvinnor i Burkina-Faso skildras i ny film". SVT (in Swedish). Retrieved 16 October 2020. 
  2. "Theresa Traore Dahlberg". Leaders Europe. Archived from the original on 18 October 2020. Retrieved 16 October 2020. 
  3. "Theresa Traore Dahlberg - Director". Momento Film. Retrieved 16 October 2020. 
  4. "Theresa Traore Dahlberg". Leaders Europe. Archived from the original on 18 October 2020. Retrieved 16 October 2020. 
  5. Barlet, Olivier (2 October 2017). "Ouaga Girls, de Theresa Traoré Dahlberg". Africultures (in French). Retrieved 16 October 2020. 
  6. Zuiderveld, Maria (25 August 2017). "Normbrytande kvinnor i Burkina-Faso skildras i ny film". SVT (in Swedish). Retrieved 16 October 2020. 
  7. "JCC 2017 : « Ouaga Girls » de Théresa Traoré Dahlberg remporte le prix CREDIF". Burkina24. 11 November 2017. Retrieved 16 October 2020. 
  8. "Theresa Traore Dahlberg receives the 2019 Beckers Art Award". Lindengruppen. 12 March 2018. Retrieved 16 October 2020. 
  9. "Theresa Traore Dahlberg". Leaders Europe. Archived from the original on 18 October 2020. Retrieved 16 October 2020. 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]