Tim Godfrey (olórin)
Tim Godfrey jẹ́ akọrin ìyìnrere Nàìjíríà. [1][2] Ó jẹ́ olókìkí jùlọ fún orin rẹ̀ Nara tí ó ṣe ní ìfọwọ́ṣowọ́pọ̀ pẹ̀lú Travis Greene .[3] Ó jẹ́ olùdásílẹ̀ àti òǹni ilé-iṣẹ́ orin Rox Nation àti olùdásílẹ̀ Xtreme Crew. [4][5]
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ìgbésí-ayẹ́ àti Iṣẹ́ ẹ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]A bí Timothy Chukwudi Godfrey ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n Oṣù Kẹjọ ọdún 1980 sí ẹbí Ọ̀gbẹ́ni àti Ìyáàfin Victor Godfrey ní Kaduna, Nàìjíríà . Òun ni ọmọ kejì tí àwọn òbí i rẹ̀ nínú àwọn ọmọ mẹ́fà tí àwọn òbí i rẹ̀ bí. Ó kọ́ ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bèrẹ̀ rẹ̀ ní Kaduna, Nàìjíríà bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpínlẹ̀ Abia ló ti wá. Ó gba oyè ịmọ̀ Dọ́kítà nínú ìmọ̀ Fine Art àti Musicology ní Trinity International University of Ambassadors, Georgia, USA ni 2018. [6]
Ìgbésí-ayé ara ẹni
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Tim Godfrey ṣe ìgbéyàwó ní Ọjọ ọ Sátidé, ọjọ́ kẹtàlélógún Oṣù Kẹrin, Ọdun 2022 pẹ̀lú ìyàwó àfẹ́sọ́nà rẹ̀ Erica, ẹni tí ó kọnu ìgbéyàwó sí ní ọjọ́ àyájọ́ olólùfẹ́.[7]
Àwọn orin
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọdún 2014-2017
S/N | Orúkọ Orin | Ọdún |
---|---|---|
1 | Ìwọ ni Ọlọ́run | Ọdún 2014 |
2 | Àmín | |
3 | Ó dára | |
4 | Oríkì | |
5 | Mo sìn | |
6 | Olùgbọ́ ti Ọ̀kan | |
7 | Ọlọ́run Alágbára | |
8 | Omemma | |
9 | Kosi | |
10 | Ahaa | Ọdún 2016 |
11 | Ó dára | 2017 |
12 | Ekelebe | |
13 | Idinma | |
14 | Chizobam | |
15 | Lai Lai | |
16 | Onyedikagi | |
17 | Sin Medley | |
18 | Ọjọ́ dáradára | |
19 | Akọni | |
20 | Agidigba | |
21 | Fi ìbùkún fún Olúwa | |
22 | Àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ń rìn | |
23 | Ìkígbe Ogun | |
24 | Jigidem | |
25 | Tí ó tóbi |
- ↑ Alonge, Ayo. "My grass to grace story – Tim Godfrey, gospel musician". Sunnews Online. Retrieved 4 February 2019.
- ↑ Ibori, Diana. "Tim Godfrey biography". Legit. Retrieved 4 February 2019.
- ↑ "Tim Godfrey Drops "NARA" ft. Travis Greene". gmusicplus (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-10-30. Retrieved 2022-04-23.
- ↑ "Tim Godfrey unveils 'Rox Nation'". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-03-31. Archived from the original on 2023-04-27. Retrieved 2023-04-22.
- ↑ BP-Pub-1 (2016-10-11). "Biography Of Tim Godfrey - Gospel Artist". Believers Portal (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-04-22.
- ↑ "Tim Godfrey Receives Doctorate Degree At Trinity International University". SelahAfrik (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-10-30. Retrieved 2021-02-20.
- ↑ "Tim Godfrey Receives Doctorate Degree At Trinity International University". NigerdeltaConnect (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-10-30. Retrieved 2022-04-23.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]