Tobore Ovuorie
Tobore Ovuorie jẹ́ akọròyìn, olóòtú ọ̀rọ̀ ìlera àti olùṣèwádìí àgbà pẹ̀lú Premium Times.[1]
Ìgbésí ayé
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ovuorie ṣe àtẹ̀jáde ìwé àkọ́kọ́ rẹ̀ ní ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún.[2] Ó bẹ̀rẹ̀ ìwádìí abélé kan tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ Inside Nigeria's Ruthless Human trafficking Mafia ní ọdún 2013, èyí tí Premium Times gbé jáde ní ọdún 2014.[3]
Ovuorie bèrẹ̀ $5,000,000 (èyí tó ń lọ bíi N225million) láti ọwọ́ ilé-iṣẹ́ EbonyLife fún ìtẹ̀jáde fíìmù kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Oloture láìgbé oríyìn fún un. Ó sọ pé fíìmù náà jẹ́ àfihàn ìrírí rẹ̀ nínú Inside Nigeria's Ruthless Human trafficking Mafia.[4] Ẹni tó ni ilé-iṣẹ́ náà, ìyẹn Mo Abudu sọ pé iṣẹ́ ìtàn àròsọ ni fíìmù náà, àti pé oríṣiríṣi ìṣẹ̀lẹ̀ òtítọ́ ló mu lóríyá. Àlàyé náà tún ní àfikún pé fìímu Oloture náà wáyé látàrí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn ilé-iṣẹ́ pẹ̀lú àkọsílẹ̀ orísiríṣi lórí gbígbé ènìyàn káàkiri àti ìbálòpọ̀ àfipámúni.[5]
Àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọmọbìnrin náà ti gba àmì-ẹ̀yẹ Deutsche Welle (DW) ti ọduhn 2021, èyí tó jẹ́ Freedom of Speech Award.[6]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "I almost lost my life in this undercover project but I have no regret — PREMIUM TIMES’ Tobore Ovuorie | Premium Times Human Trafficking Investigation" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-11-30.
- ↑ "Tobore Ovuorie's schedule for GIJC15". gijc15.sched.com. Retrieved 2021-11-30.
- ↑ "PREMIUM TIMES Human Trafficking Expose: Tobore's Diary" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2014-02-06. Retrieved 2021-11-30.
- ↑ Adebayo, Tireni (2020-11-13). "Oloture: Journalist Tobore Ovuorie Demands N225million from Mo Abudu". Kemi Filani News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-12-01.
- ↑ Williams, Patricia R. (2018-01-31). Identification of client involvement in sex trafficking in Mississippi. http://dx.doi.org/10.1080/23761407.2018.1430645.
- ↑ "Investigative journalist Tobore Ovuorie wins DW Freedom of Speech Award 2021". Media Career Services (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-05-04. Archived from the original on 2021-12-01. Retrieved 2021-12-01.