Jump to content

Tunde Oladimeji

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Túndé Ọládiméjì jẹ́ onífíìmù-ìfiṣerántí, òṣeré, olùdarí-eré àti àtọkún orí tẹlifíṣàn ọmọ orílẹ́-èdè Nàìjíríà. Aṣáájú ni nínú àwọn onífíìmù-ìfiṣèrántí ní èdè abínibí ní Nàìjíríà. Òun ní olùdarí Aàjírebí, ètò òwúrọ̀ tí wọ́n ṣe àfihàn rẹ́ lórí Africa Magic Yorùbá.

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti iṣẹ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Ọládiméjì ní ìlú Ìsẹ́yìn, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Nàìjíríà. Olùkọ́ ní ìyá rẹ̀, tí bàbá rẹ̀ sì jẹ́ wọ̀nlẹ̀-wọ̀nlẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ fíìmù ṣíṣe ní Yunifásítì Ìbàdàn níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè tí ó sì jẹ́ akọ́ọ̀wọ́rìn olótùú fíìmù àkọ́kọ́ rẹ̀, ìwé olóògbé Ọládẹ̀jọ Òkédìjí tí ó lọ ní 1972 tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ Àgbàlagbà Akàn tí ó fi ojú rẹ̀ mọlẹ́.

Ó kó ipa gbòógì nínú Bọ̀rọ̀kìní, eré orí-ìtàgé kúkúrú orí tẹlifíṣàn ó sì kópa olù eré nínú fíìmù Akékaka, fíìmù tí Jayé Kútì gbé jáde ti o se àfihàn Fẹ́mi Adébáyọ̀, Mercy Aigbe àti Ẹ̀bùn Olóyèdé Ọlá-Ìyá Bákan náà ni ó jẹ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ olótùú Amstel. Malta Box Office sáà karùn-ún àti olùdarí Aàjírebí. Ó ṣe àtọkún Àràḿbarà ó sì jẹ́ akọ́ọ̀wọ́rìn olùdarí Ẹlẹ́yinjú àánú, Àràḿbarà.[1]

Ọládiméjì ní olótùú Àwọn Ètò ìfiṣèrántí Àjogúnbá Yorùbá (Yorùbá Heritage Documentary Series). Wọ́n yàn Ìbàdàn ọkàn lára àwọn ètò ìfiṣèrántí nínú ìpele ìfiṣèrántí tí ó peregede jù ní àmì-ẹ̀yẹ Africa Magic Viewer's Choice 2020. Àwọn  ìfiṣèrántí mìíràn nínú ètò ni Èkó Àkéte, Abẹ́òkúta ilẹ̀ Ẹ̀gbá, Ifẹ̀ Oòyè àti Òṣogbo Òròkí.[2]

Àwọn itọ́ka sí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Meet Tunde Oladimeji, The AMVCA Nominee Who's Determined To Keep Telling Nigerian Stories". Opera News. 2020-03-17. Archived from the original on 2021-10-05. Retrieved 2021-09-29. 
  2. "Being nominated for AMVCA is an achievement —Oladimeji". Tribune Online. 2020-02-23. Retrieved 2021-09-29.